Wọ́n fẹ́ pa wá run Kí wọ́n ráàyè gba ilẹ̀ wa ni.Olúwa kò sì ní fún wọn ṣe…Caleb Muftwang

Gómìnà ìpínlẹ̀ Benue,Caleb Muftwang ti fẹ̀ṣùn kan àwọn Fúlàní darandaran tí wọ́n ń pa àwọn ènìyàn ipinlẹ̀ rẹ̀ bí ẹni pẹran pé àlùwàlá ológìnní wọn,ọgbọ́n àtikẹ́ranjẹ ni.Kò sí ète àti ọgbọ́n méjì tí wọ́n ń dá jù kí wọ́n ó pa àwọn ènìyàn òun run Kí wọ́n lè gbà ilẹ̀ wọn lọ.

Òní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹrin ló fí ojú ọ̀rọ̀ yìí léde nígbà tó ń dáhùn àwọn ìbéèrè lọ́kan-ò-jọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ Tẹlifísàn Tvc nipa àkọlù tó wáyé lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí ní ìpínlẹ̀ rẹ̀ àti ìpínlẹ̀ Plateau nínú èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá ti ṣòfò .

Muftwang tẹ̀ síwájú pé ìròmì àwọn kọ̀lọ̀rànsí ẹ̀dá náà tó ń jó kò sàìní àtìlẹ́yìn àwọn Bàṣèjẹ́ obì tó ń ṣo lẹ́ẹ̀rùn Alóókọlóókì kan láwùjọ.

Ó ní kò sí ìgbà tí ilẹ̀ kò ní mọ́ bá alákìísà wọn tó ń jó lórù ati pé bí irọ́ bá lọ lógún ọdún, ọjọ́ kan ṣoṣo ní òdodo yóò le bá.Ẹni tó ta ọfà ṣókè tó yídó borí,bí ọba ayé kò bá rí I,ó dájú pé tọ̀run ń wò ó.

Gómìnà wàá rọ Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú kó jọ̀wọ́ jàre túbọ̀ gbọnwọ́ sí ètò àbò ní àwọn ìpínlẹ̀ méjèèjì kí àwọn èèyàn òun lè sun àsùnforílésùká.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×