
Alága ágbáríjọ àwọn Gómìnà Onítẹ̀síwájú ti wọ́n gun ẹṣin ẹgbẹ́ òṣèlú APC dé orí àléfà tíì tún ṣe Gómìnà ìpínlẹ̀ Imo, Ọ̀gbẹ́ni Hope Uzodinma kó àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ nínú èyí tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó,Lucky Orímisàn Aiyédàtiwa jẹ́ ọ̀kan lára wọn ṣodi lọ kí Ààrẹ àná, Muhammad Buhari nílé rẹ̀ lánà-án ní ìlú Kaduna.

Nígbà tó ń kí wọn káàbọ̀, Buhari kí wọ́n kú ìdodimú,ó rọ̀ wọ́n kí wọ́n mú ìgbáyégbádùn àwọn ènìyàn tó dìbò fún wọn ní ọ̀kúnkúndùn.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, alága ẹgbẹ́ àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní kí ààrẹ má ṣe bínú pé ó pe kí àwọn tó wá kì I kú ọdún.
Wọ́n wá gba àdúà pé ẹ̀mí rẹ̀ yóò ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láyé.
Nígbà

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
