Ohaneye,Mamman àtàwọ́n mẹ́ta mìíràn lọ
Bianca Ojukwu,Yuwatda àtàwọn marun-un mìíràn wole

Láti fòpin sí awuyewuye tó ti ń jà ràn-ìn-ràn-ìn nílẹ̀ lórí ìpinnu ìjọba láti tún ìgbìmọ̀ aṣèjọba ilẹ̀ yìí sọ bí ẹní sọ igbá,Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú ti fẹ̀ẹ̀kùlé ọwọ́ júwe ilé fún àwọn Mínísítà ìjọba rè márùn-ún nígbà tí àwọn méje miiran rí oore-ọ̀fẹ́ láti di Mínísítà gbà
Àwọn tí wọ́n ní kí wọ́n máa relé wọn ni:Iju Ken(Mínísítà Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin),Lọlá Ade John (Ìrìnàjò Afẹ́), Ọ̀jọ̀gbọ́n Tahir Mamman (Ètò Ẹ̀kọ́) Abdullah Gwarzo(Mínísítà Àbẹ́lé fún ilégbèé àti ìdàgbàsókè ilú ńlá) Ọ̀mọ̀wé Jamilah Ibrahim (ìdàgbàsókè àwọn ọ̀dọ́)
Ẹ̀wẹ̀, àwọn méje mìíràn ní Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú fi orúkọ wọn ránṣẹ sí ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin fún ìfòǹtẹ̀lù fún ipò Mínísítà.Àwọn náà ni: Ọ̀mọ̀wé Nentawe Yilwatda(Ètò Bántánṣẹ̀ẹ́), Mohammed Dingyadi(Ọ̀rọ̀ Àwọn Òṣìṣẹ́), Bianca Ojukwu (Mínísítà Àbẹ́lé fún Ọ̀rọ̀ ilẹ̀ Òkèèrè),Jùmọ̀kẹ́ Odùwọlé(Ìdáṣẹ́sílẹ̀ àti Ọ̀rọ̀ Okòwò),Idi Moukhtar Maiha (Ìdàgbàsókè nǹkan Ọ̀ṣìn), Yusuf Atta(Mínísítà Àbẹ́lé fún ilégbèé àti ìdàgbàsókè ilú ńlá) àti Ọ̀mọ̀wé Suwaibu Ahmed (Mínísítà Àbẹ́lé fún Ètò Ẹ̀kọ́)
Ti ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ yii bá buwọ́ lu ìyànsípò Bianca Ojukwu tii ṣe Ògbóhùntarìgì ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APGA gẹ́gẹ́ bíi Mínísítà, Òun ni yóò jẹ́ Mínísítà Kejì tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ninu ìṣèjọba Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú.Ẹni àkọ́kọ́ ni Mínísítà Olú-ìlú ilẹ̀ wa, Nyesom Wike tó wá láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
