
Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà,Bọ́lá Tinúbú ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ tí yóò ṣe ọ̀fíntótó òhun ìwádìí tó múná dóko lórí ọ̀nà àátọ̀ tí a fi lè ṣe ètò Ìkànìyàn tí yóò gbé oúnjẹ fún ẹgbẹ́ gbàwo bọ̀ ní ilẹ̀ Nàìjíríà.
Òní ọjọ́rùú ni wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ náà ní ìlú Abuja.Alága ìgbìmò náà sì ni Mínísítà fún ètò ìṣúná nílẹ̀ wa,Sẹ́nétọ̀ Atiku Bagudu.
Lára àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ni Mínísítà fún ètò ìròyìn, Mohammed Idris, alága àjọ elétò ìkànìyàn nílẹ̀ wa,Nasir Issa Kwarra tii tún í ṣe akọ̀wé ìgbìmọ̀ náà àti àwọn èèkàn ìlú mìíràn
Ọ̀ṣẹ̀ mẹ́ta péré ni ìgbìmò náà ní láti jábọ̀ ìwádìí rẹ̀.
Nígbà tó ń ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ náà, olórí àwọn òṣìṣẹ́ ní ọọ́fíìsì Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà, Họnọrèbù Fẹ́mi Gbàjàbíàmílà tó ṣojú Ààrẹ níbi ayẹyẹ ọ̀hún ní kò sí ohun tó dára tó ká mọ iye ara wa.Ó ní eléyìí ni yóò jẹ́ kí ìjọba mọ odó ti yóò da ọ̀rúnlá sí nínú ọ̀rọ̀ àńsààtò fún ará ìlú.
Ààrẹ Tinúbú ní kí ìgbìmò náà má gbàgbé láti da ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé rò nínú ètò Ìkànìyàn náà nítorí bí ayé ti ń yí ló ṣe yẹ kí á máa bá ayé yí.
Nígbà tó ń fèsì, alága ìgbìmọ̀ náà tii tún ṣe Mínísítà fún ètò ìṣúná,Atiku Bagudu ní ìmọràn tí Tinúbú gba àwọn elétò ìkànìyàn lọ́dun 2003 nígbà tó jẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó ran àjọ náà lọ́wọ́ púpò nígbà tí wọ́n ṣe ètò ìkànìyàn lọ́dun 2006.
Bagudu tẹ̀ síwájú pé ó dá òun lójú pé dídùn lọsàn ètò náà yóò ṣo
Ọdún 2006 ni a ti ṣe ètò ìkànìyàn gbẹ̀yìn ní ilẹ̀ Nàìjíríà.Àpapọ̀ àwọn ènìyàn ilẹ̀ yìí nígbà náà sì jẹ́ Ogóje mílíọ̀nù, ẹgbẹ̀rún lọ́nà òjìléerínwó ó dín mẹ́sàn-án ati ẹgbẹrin ó dín mẹ́wàá (140,431,790)
Nínú àpapọ̀ òǹkà ènìyàn yìí, Mílíọ̀nù mọ́kànkéláàádọ́rin, ẹgbẹ̀rún lọ́nà òjìlélọ́ọ̀ọ́dúrún ó lé márùnún àti ọ̀rìnlénírinwó ó lé mẹ́jọ(71,345,488) nígbà tí àwọn obìnrin jẹ́ Mílíọ̀nù mọ́kàndínláàádọ́rin, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndin láàdọ́rin ó dínkan àti méjìlélọ́ọ̀ọ́dúnrún.(69,086,302)
Awuyewuye wáyé lórí ọ̀rọ̀ pé ọkùnrin pọ̀ ju obinrin lọ nítorí ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn ni pé obìrin pọ̀ ju ọkùnrin lọ.Títi di àsìkò yìí ni àwọn ènìyàn ń fojú láìfí wo èsì ìkànìyàn náà

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
