Pope Francis yóò wọ káà ilẹ̀ sùn lónìí….. Vatican

Pápà mímọ́ jùlọ ti ìjọ Àgùdà lágbàáyé,Pápà Francis yóò wọ káà ilẹ̀ sùn lónìí.

Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti olú ilé ìjọ Àgùdà ní Vatican ṣe àlàyé pé wọn yóò dé posi tí wọ́n fi gbé òkú ènìyàn Ọlọ́run náà pa lẹyìn tí wọ́n ti tẹ́ ẹ ni ìtẹ́ ẹ̀yẹ káàkiri orílẹ̀-èdè náà.

Ẹní ọdún méjìdínláàádọ́rùn-ún ni Pápà kó tó kú.

Ìlú Vatican ti kún àkúnwọsílẹ fún àwọn àlejò yíká àgbáyé tí wọ́n wá láti bu ẹ̀yẹ ìkẹhìn fún ìríjú Elédùmarè náà.Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin àgbà,Sẹ́nétọ̀ Godswill Akpabio ni yóò kó àwọn ikọ̀ orilẹ-èdè Nàìjíríà ṣòdí níbi ayẹyẹ náà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×