
Láti inú oṣù Kejì tí òjòjò ti ń ṣògún Pápà mímọ́ jùlọ Fransisco ti ìjọ Àgùdà lágbàáyé,ọọ́fíìsì Alukoro àgbà fún orílẹ̀-èdè Vertican fi àwòrán rẹ̀ léde ní ọjọ́ àìkú àná nibi tó ti ń ṣe àdúà níwájú tẹ́ḿpìlì mímọ́ tó wà ní àjà kẹwàá ní Gameili Polyclinic tó wà ní ilẹ̀ Rome .
Bí-ó-tilẹ̀-jẹ́-pé Pápà mímọ́ ṣe àdúà náà lórí ìjokò ni ,wọ́n kò si tíì máàa gba àlejò kankan, ṣùgbọ́n ẹ̀rí máa jẹ́ mi nìṣó ṣe àfihàn pé ara baba ti balẹ̀,ẹ̀kó ti ń wọlé,ewé ti ń jáde.
Fọ́tò yìí ló fi òpin sí ọ̀pọ̀ awuyewuye tó tí ń fò káàkiri lórí ìlera ẹni àkọ́kọ́ láwùjọ àwọn Kristẹni ọ̀hún.Ilé ìwòsàn Gameili ní Rome wá fi ìgbàgbọ sọ pé kò le pẹ́ kò sì lè jìnnà tí baba yóò fi padà sí ẹnu ìṣẹ́.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
