
Yorùbá bọ̀, wọ́n ní ìwà rere ni ẹ̀ṣọ́ ènìyàn àti pé ìwà ní ọmọ olóore ń jẹ.Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló ṣe rí fún èèkàn ìlú tó mú rírónilágbára àti ìgbáyégbádùn ọmọnìyàn lọ́kùnkúndùn nnì,Amb.Dr.Emeka Egene Chimezie. Ẹni ti àjọ kan tí kò rọ̀gbọ̀kú lé ìjọba fí oyè AFRILA 3 0.2025 dá lọ́lá.
Ọ̀gbẹ́ni Chimezie ní Olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ Emirald Global tó mú ìwòsàn ará ìlú tòhun-tìgbáyégbádùn wọn ní ìbàádà.
Ọjọ́ Àbámẹ́ta ọjọ́ karùn-ún oṣù yìí ni ayẹyẹ náà yóò wáyé ní Army Officers Mess tó wà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ Aso Clinic,Mambila Barack, Abuja ní déédéé agogo méta ọ̀sán.
Gbogbo àwọn aṣáájú àti léèkànléèkàn àwùjọ ni wọ́n tí ń rọ̀jò ìkíni lé olórí rere ẹ̀dá yìí lórí.Lára wọn ni Dókítà Sussan Okonkwo tó jẹ́ ọ̀kan lára lọ́gàálọ̀gàá ilé iṣẹ Emirald Global.Arábìnrin yìí fi ìdùnnú ti kó lẹ́gbẹ́ hàn sí ìfàmì-ẹ̀yẹ-dánilọ́lá náà.Ó sì gbàdúrà fún ìtẹ̀síwájú ohun dáradára nínú ayé wọn.
Òkò kan ni Olùdásílẹ̀ Emirald Global yóò fi fi pa ẹyẹ méjì nítorí nǹkan ẹni kìí di méjì kí inú ó bíni, ìdánilékòó lórí ànfààní ìlera,ìtanijí lórí ìpèṣè lọ́kan-ò-jọ̀kan àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ yóò wáyé ní ìlú Abuja yìí bákan náà láàrin ọjọ́ kẹfà sí ìkeje oṣù yìí bákan náà.Ètò sì ti tò tán fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Atóríẹnitíkòṣunwọ̀nṣe náà.

Gbogbo àwọn Emirald Global ní ìlú Àkúrẹ́ (FFF Team) náà ń kí Olùdásílẹ̀ wa kú oríire.A sì ń ṣe àdúrà pé òkèòkè lẹmu ń ru sí, lókèlókè lẹ ó máa wà oo.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
