
Kò jẹ́ tuntun mọ́ pé Ọkùnrin olókó kòmẹbí kan ní ilẹ̀ Equitorial Guinea, Bathaza Ebang Egonga bá irínwó obìnrin lò pọ̀ tó sì ṣe fídíò ìbálòpọ̀ náà síta tó bẹ́ẹ̀ tó fi di tọ́rọ́-fọ́n-kálé káàkiri àgbáyé .Bí ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn ṣe kòrò ojú sí ìwà ibi yìí tó, Olólùfẹ́ Eré ìdárayá kan ní ilẹ̀ Uganda ti yan Bathaza Ebang Egonga láàyò tó bẹ́ẹ̀ tó fi ṣe àkànṣe ẹ̀wù mọ́n-an-ràn tí a mọ̀ sí Jersey tí ó kọ orúkọ ọkùnrin náà àti ìwà ìbàjẹ́ tí ó hù sí ara aṣọ náà.
Ohun tí ó kọ sí ara ẹ̀wù náà ni “Bathaza Ebang Egonga:400″ tí ó túmọ̀ sí Bathaza Ebang Egonga: Ẹni tó bá irínwó obìnrin lò pọ̀.Tayọ̀tayọ̀ ni Olólùfẹ́ Eré ìdárayá yìí fi ń wọ ẹ̀wù yìí lọ sí ibi yòówù tó bá ti lọ wo ìran eré ìdárayá.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló ṣe ìfìdímúlẹ̀ òwe Yorùbá tó ní Ẹ̀kọ̀ ẹlẹ́kọ̀ ni ẹ̀gbà ẹlẹ́gbà àti pé “Bí ènìyàn bá ń gún iyán bọ́ ìlú, yóò ní ọ̀tá, bí ènìyàn bá sì ń sọ òkò sí ọjà, yóò ní ọ̀rẹ́ “
Ìtàn kò ní gbàgbé Bathaza bọ̀rọ̀bọ̀rọ̀ fún ipa takun-takun tó kó láti tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin lọ́rùn pẹ̀lú ọ̀pá Mósè rẹ̀ tó gùn dọ̀gìà bíi ti ẹṣin.Bí-ó-tilẹ̀-jẹ́-pé ìdílé tí ìwà ìbàjẹ́ tí ó hù yìí dàrú kò lóǹkà tí ẹgbàágbèje Obìnrin sì pa ara wọn nitori ìtìjú.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
