
Lójijì ni ìdùnnú òhun ayọ̀ sáré di ìbànújẹ níbi ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ kan ni Vancouver Fillipino lálẹ́ àná Sátidé nígbà tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan yà bàrá tó sì ń pa àwọn ènìyàn bí ẹni pẹran.
Ìbí ayẹyẹ náà tó kún dẹ́nu fún àwọn àgbà, ọmọdé lọ́kùnrin-lóbìnrin tí kálukú ń dá múṣò ojú rí ọdún, tí jíjẹ-mímu kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ sí ni kàràm̀bàní ọlọ́kọ̀ náà ti yà lọ bá wọn tó pa àwọn kan tó sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní èṣe.
Àjọ Ọlọ́pàá agbègbè náà fi léde pé ọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdún ọmọ Vancouver tó wa mọ́tò náà ti ń ṣẹ́jú pàkò lákóló àwọn.Wọ́n ti síwájú pé ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu lórí ohun tó fa ìjàm̀bá náà.
Olóòtú ìjọba ilẹ̀ náà,Mark Carney nínú ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn rẹ̀ tó fi léde lórí ìkànnì abẹ́yẹfò X tí a mọ̀ sí twitter rẹ̀ ló ti ní “Àrùn tó ń ṣe ogójì ló ń ṣe ọ̀ọ́dúnrún,ohun tó ń ṣe abọ́yadé, gbogbo ọlọ́ya ló ń ṣe.Àjálù tó ṣẹlẹ̀ dùn wá.Kódà,bí ìgbà tí ènìyàn fi ọwọ́ sọ ògiri ló ṣe dùn wá.Ìjọba ń kẹ́dùn pẹ̀lú yín.Olúwa yóò pinnu àìdára.A kò ní rí irú rẹ̀ mọ́“
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀,Alága ìjọba agbègbè náà,Sim Ken kẹ́dùn gidigidi ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ẹlẹsẹ onimọ́tò náà kò ní lọ láìjìyà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
