Ọ̀kọ̀ Àjàgbé Elépo Tó Ṣubú Gbẹ̀mí ÈnìyànNí Ìlú Ọ̀rẹ̀

Ọjọ́ burúkú Èsù gbomi mu ni ọjọ́ Sátidé, ọjọ́ kọkànlélógún oṣù Kejìlá ọdún 2024 jẹ́ fún àwọn ìdílé mélòó kan ní ìlú Ọ̀rẹ̀ ní bí wọ́n ti pàdánù ènìyàn wọn níbi ìjàm̀bá ọkọ̀ àjàgbé tó gbé epo bentiroolu lọ́nà Èkó tó sì tàkìtì tó gbiná lẹ́yẹ-ò-sọkà.

Oníròyìn Naijanotes,Ẹdúnjọbí Àkànmú tó tọpinpin ìṣẹ̀lẹ̀ náà jábọ̀ pé ohun tó fa ìṣubú ọkọ̀ náà kò yéèyàn ṣùgbọ́n kété tí ọkọ̀ náà fi ẹ̀yìn lélẹ̀ ní kọ̀lọ̀rànsí Ọkùnrin kan ti gbé ládugbó lọ sí ibẹ̀ láti gbọ́n epo.Ibi tó ti ń gbìyànjú èyí ní iná ti ṣẹ́yọ tó sì jó ọkùnrin náà gúdúgúdú.

Ìjàm̀bá iná tó máa ń ṣẹ́yọ látàrí ìṣubú ọkọ̀ àjàgbé agbépo ló ti ń di kànlekànle ní ìlú Ọ̀rẹ̀.Ti a kò bá gbàgbé,ó tó irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí bíi mẹ́ta tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún tó ń ré kọjá lọ yìí.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×