Ojukwu kọ́ ló yọ Awólọ́wọ̀ lẹ́wọ̀n;Gowon Ni…Omokri

Irọ́ funfun báláú ni àhesọ ọ̀rọ̀ kántankàntan tí àwọn Aláìnífun nínú ẹ̀dá tí wọ́n jìnnà sí làákàyè bíi sánmà jìnnà sílẹ̀ kan ń gbé kiri pé Olórí orílẹ̀-èdè Biafra tó dá ogun abẹ́lé Nàìjíríà sílẹ̀ nnì, Ọ̀gágun Chukwuemeka Odumegwu Ojukwu ló yọ̀ǹda Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n ní ìlú Calabar lọ́dún 1966.

Olùbádámọ̀ràn pàtàkì sí Ààrẹ ìjẹta,Goodluck Jonathan lórí ọ̀rọ̀ ìbáraẹnisọ̀rọ̀,Reno Omokri ló fojú ọ̀rọ̀ yìí léde lórí ìkànnì abẹ́yẹfò twitter ti a mọ̀ sí X rè lọ́jọ́ àìkú àná.

Bí a kò bá ní gbàgbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníròyìn lórí ìtàkùn ayélujára tí wọ́n wá láti ìhà ẹ̀yà kan ló ti ń sọ̀rọ̀ pé Ojukwu ló yọ Awólọ́wọ̀ kúrò lẹ́wọ̀n pẹ̀lú ètè àti gbárùkù tì í nínú ète rẹ̀ láti ja ogun abẹ́lé. Àwọn Oníròyìn ẹlẹ́jẹ̀ náà wá tẹ̀ síwájú pé Awólọ́wọ̀ dalẹ̀ Ojukwu kò sì tẹ̀lé àdéhùn mọ́ nígbà tí ará tù ú tán. Kàkà kí ọkọ Dídéolú fọwọ́ ti Ojukwu tó ṣe é lóore lẹ́yìn,Gowon tí kò rí tirẹ̀ rò ló gbájúmọ́.

Ṣé bí ọmọdé bá kọ iyán alẹ́,àgbà á fi ìtàn balẹ̀ àti pé ẹni tó bá fẹ́ jẹ ogúnkógún,ìtànkítàn ni yóò máa pa .Láti fi òpin sí ìwà Àńfúnni-léèrí-í-jẹ ni Omokri fi wọ inú àká ìtàn lọ tó sì mú ẹ̀rí òkè yẹn wá

Àkọsílẹ̀ tí kò ní ẹja-n-bákàn nínú tó wà lókè yẹn fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọjọ́ kejìlá oṣù kẹjọ ọdún 1966 ni Ọ̀gágun àgbà Yakubu Gowon fọwọ́ sí ìwé ìtúsílẹ̀ àgbà Olóṣèlú náà.Bí orúkọ àwọn tó gba ìdáǹdè ṣe hàn nínú ìwé náà nìyii:

(1) Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀

(2) Olóyè Lateef Káyọ̀dé Jákànńdè

(3) Anthony Eronsele Enahoro

(4) Michael Adédàpọ̀ Omísadé

(5) Sunday Ebiotomo

(6)Effiong Okon Eyong

(7) Samuel Àkànbí Onítìrí.

Aluwaya òhun òfégè ní ọ̀rọ̀ tí kò bá ní ẹlẹ́rìí.Pẹ̀lú ẹ̀ri yìí, òpin yóò dé bá Àríìrísọ ọ̀rọ̀ lórí ẹni gan-an pàtó tó yọ Awólọ́wọ̀ kúrò lẹ́wọ̀n.

1 thought on “Ojukwu kọ́ ló yọ Awólọ́wọ̀ lẹ́wọ̀n;Gowon Ni…Omokri”

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×