
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa, Họnọrèbù Andrew Ògúnṣakin ti sọ pé ìdàgbàsókè ìjọba Ìbílẹ̀ Òkìtìpupa ló jẹ òun lógun.Ògúnṣakin ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń bá àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ náà sọ̀rọ̀ níbi àdúrà ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kẹrin tó wáyé ní gbọ̀ngàn ìjọba ìbílẹ̀ náà ní ìlú Òkìtìpupa.
Alága gbé òṣùbà fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ òhun àtìlẹ́yìn ti kò lẹ́gbẹ́ tí wọ́n ń fún ìjọba òun. Ó wá rọ̀ wọ́n kí wọ́n má ṣe jẹ́ kó rẹ̀ wọ́n nínú akitiyan wọn láti jáwé sóbì ìdàgbàsókè ìjọba Ìbílẹ̀ Òkìtìpupa.
Sáájú ni olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ náà,Òmọ ọba Ọjọmọ ti dúpẹ́ lọ́wọ́ alága àti ìsọǹgbè rẹ̀ nítorí pé wọn kìí fi ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa játàáà.Ṣé bí awo bá kì fúnni,a ń kì fún awo padà ni,ó wá pè fún iṣẹ́ takuntakun láti ọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́.Ó ní nípa mímú iṣẹ́ ní ọ̀kúnkúndùn ní yóò se móríyá fún alága láti lè tẹ̀ síwájú nínú dáradára ṣiṣe fún àwọn òṣìṣẹ́ àti ará ìlú.

Àlùfáà Ayọ̀kúnlé tó fí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ awọn ènìyàn níbi àdúrà náà sọ̀rọ̀ nípa pàtàkì ìdúpẹ́.Ìwé Onísáàmù orí ogóje ó dín mẹrin, ẹsẹ kìíní ló fi ṣe ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ ìwàásù rẹ̀.Ó ní afibisólóore ẹ̀dá alààyè ní kìí dupẹ.Ó gba awọn ènìyàn ní ìyànjú kí wọ́n jẹ́ kí ọpẹ́ wọn máa pọ̀ ju ìbéèrè wọn lọ nítorí bí ènìyàn bá dúpẹ́ ore àná, ó dì dandan kó gba òmíràn
Lẹ́yin ìwàásù àti àdúrà ni alága, Họnọrèbù Andrew Ògúnṣakin fí ẹ̀rọ Pianó kan ta ẹgbẹ́ Akọrin ijọba ìbílẹ̀ náà lọ́rẹ̀.

Igbákejì alága,akọ̀wé ìjọba ìbílẹ̀, olórí àwọn òṣìṣẹ́ (HOLGA),alága ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ tí a mọ̀ sí NULGE , gbogbo àwọn olùdarí ẹ̀ka gbogbo tó fi mọ́ gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ pátápátá.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
