
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó, Lucky Orímisàn Aiyédàtiwa ti sọ yanya pé ó di ọjọ́ kẹwàá oṣù kejì ọdún yìí kí wọ́n tó búra fún àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ méjèèjìdínlógún tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ Oǹdó.
Gómìnà yajúyamú ọ̀rọ̀ yìí léyìn ìpàdé ìdákọ́ńkọ́ alátìlẹ̀kùnmọ́rí ṣe pẹ̀lú àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ní ìlú Àkúrẹ́. Ó ní èrèdí ìsúnsíwájú yìí ní láti bu ọlá ìkẹyìn fún akọ̀wé ìpínlẹ̀ Oǹdó, Họnọrébù Temídayọ̀ Olúwátúyì ti gbogbo ènìyàn mò sí Tùkànà kú lọ́dún tó kọjá lọ.
Ìjàm̀bá mọ́tò ni Tùkànà ni, eleyii ló sì fa ikú rẹ̀ nitori àìgbádùn látári èṣè tí ó ṣe nibi ìjàm̀bá náà.
Ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ nínú osù Kejì ni ìṣìnkú Tùkànà yóò bẹ̀rẹ̀ titi di ọjọ keje oṣù kejì táa wà yìí.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
