Ọ̀gẹ̀dẹ̀ Ń bàjẹ́,A Ló Ń Pọ́n;Ayé Ń bàjẹ́ A Ní Ọ̀làjú Ni.

Nígbà tí ìwà ṣẹ̀ ní ilẹ̀ Nàìjíríà,ti eku ń dún bí eku tí ẹyẹ ń ké bí ẹyẹ tí ọmọ ènìyàn ń fọhùn bí ènìyàn, Wèrè nìkan ló ń rìn ní ìhòòhò.Sugbon láyé òde òni,Bàràǹdà kò jẹ́ ká mọ ọ̀lẹ Ìwó,Arúmọ́tá kò jẹ́ ká mọ Aṣòpá ní Ìlọrin.Ó ṣòro láti mọ ìyàtọ̀ láàrin wèrè àti ènìyàn gidi nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin ayé òde òni ni wọ́n ti sọ ìhòòhò di oge.

Bí eré bí eré,Àlàbọrùn ń dí ẹ̀wù,gẹ̀gẹ̀ ń di àrùn. A ò gbọ́ apẹ́ nílé ọba mọ́,a ò gbọ́ ọ̀wàrà ní ẹ̀hìnkùlé òjò, kò sí ọ̀pá kugúkugú ní ojúde Ìṣẹrimọgbe mọ́.Ohun gbogbo wá doríkodò tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀rọ̀ náà fi jọ ti ìlú Èdìdàrẹ́ tí D.O Fágúnwà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé aládùn tó kọ . Ọ̀gẹ̀dẹ̀ ń bàjẹ́ a ló ń pọ́n, ayé ń bàjẹ́ a ló ń rẹwà.ohun ti wa kò jọ wá lójú mọ́,tẹni ẹlẹ́ni tí kò dára tó ti wa la wá ń kàráámọ̀ rẹ̀.Wọ́n gba òdodo lọ́wọ́ wa,wọ́n gbé irọ́ lé wa lọ́wọ́,wọ́n yọ tinú ọ̀gẹ̀dẹ̀ jẹ tán wón fi pàpàǹdúdú sílẹ̀.

Kí á má ṣe bá Òpó lọ sí ilé Olóròó,ẹ jẹ́ kí a wo àwon fọ́tò òkè yen.Àwọn fọ́tò náà ṣe àfihàn Omidan Naijiria ní ọdún 1957 àti Omidan Nàìjíríà ọdún 2025.Ẹ̀yin náà ẹ wò ó.Taa ló jọ Ọmọlúàbí taa ló jọ Wèrè nínú àwọn méjèèjì? Taa ló jọ Àṣẹ́wó taa ló jọ Omidan?

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀,ọlọ́pọlọ pípé tó múwà-mẹ́wà ló máa ń díje gba ipò omidan.Ní báyìí,a ti sọ ọ di Gbàgede àwọn Aṣẹ́wó.Ó kúkú ṣe í ṣe kí àwọn olùṣèètò ti tọ́ gbogbo wọn wò, kó sì jẹ́ pé ẹní tí tirẹ̀ bá dún jù ni wọn á gbé apata fún.Àbí ọmọ Naijiria kọ́?tó jẹ́ pé bí wọ́n bá fi ẹyin rán wọn níṣẹ́,wọn yóò pọ́n ọn lá lójú ọ̀nà.

Kí iru ìwà ìdọ́jútì yìí ó máa baà tẹ̀ síwájú,Ó yẹ kí àwọn tí wọ́n wà ní ìgbánnu àwọn irúfẹ́ ìdíje báyìí máa ní ìn lọ́kàn pé ìdíje Aṣẹ́wó kọ́ ni àwọn ń ṣe àti pé ilẹ̀ Adúláwọ̀ la wà,A kò gbọdọ̀ sọ àṣà àti íṣe wa nù nítorí pé a fẹ́ tẹ́ àwọn kan lọ́rùn. Bí Onígbá bá ti pe igbá rẹ ni a ń bá a pè é.Orúkọ tí a bá sọ ara wa ní wọn ó pè wá

Àṣà Àtọ̀húnrìnwá tí a gbà t àwọn ọmọ wa di Aláìlójútì.Ọ̀gẹ̀dẹ̀ ń bàjẹ́,a ló ń pọ́nk

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×