Obi Cubana! Bá mi gbé ìràwọ̀ mi tí o lò,Kí o sì wá gbé ọmọ rẹ oo! …Helen Ati

Ọmọ ilẹ̀ Kenya tii ṣe ọ̀kan lára àwọn àlè tó bímọ fún gbajúgbajà olówó Aríayẹyẹ yiọ̀ nnì,Pascal Okechukwu,tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Obi Cubana ló ti fi igbe ta pé kó wá gba ọmọ tí òun bí fún un.

Àná ló ké lóhùn rara lórí ìkànnì abánidọ́rẹ̀ẹ́ Instagram rẹ̀.Helen sọ pé abẹ́rẹ́ tó lókùn nídìí ni Obi Cubana nitori Babalóòsà Nssuka ni Babańgbẹ̀ẹ́jọ́ rẹ̀ tí òun yóò fi ẹjọ́ rẹ̀ sùn.

Gẹ́gẹ́ bó ti wí ọ ní ‘Ènìyàn burúkú tí a kìí jí rí ni Obi Cubana.Ó lo ìràwọ̀ mi,ó fún mi lóyún, mo sì bí ọmọkunrin kan fún un ti ó ní kìí ṣe òun lòún ni ín.Mo sì ní kó wá lọ ṣe àyẹ̀wò DNA.,ó ń sá kiri.Irọ́ lo pa,ní ò le nìkan tọ́jú ọmọ.’

Pẹ̀lú ìkanra ni Helen Ati ń tu bíi ejò tó ní kò sí ònà ti obi Cubana le gbe gba kí òun má ṣe fi patiẹ jẹ ẹ́.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×