Ó ti dé oo!Aya Gómìnà Aiyédàtiwa Wọ̀lú;Ọ̀tẹ̀ bùṣe.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye ló ti ń wáyé l’órí bí aya Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó kò ti sí ní ilé ìjọba.Kóda, nígbà tí iná òṣèlú ń jò hììhìì! Àwọn olóṣèlú fi sọ̀rọ̀ lásìkò ìpolongo ìbò pé kí wọn má ṣe dìbò fún àpọ́n láti di Gómìnà nitori yóò ṣòro fún ẹni tí kò ní aya nílé láti darí odindi ìpínlẹ̀.

Ṣùgbọ́n sí ìyàlẹ́nu gbogbo ènìyàn,kúlẹ́ ni aya Gómìnà wọlé sí ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan tó wáyé ní ilé ìjósìn tó wà ní ilé ìjọba.Ní kété tí Àlùfáà tó ń wàásù ti gán-ánní rẹ̀ ló ti ń kíi ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá pé Her Excellency!Her Excellency!! ẹ káàbọ̀ m

Báyìí ni igbe ṣe ta ní tìbú-tòòró ilé ìjósìn náà.Ìpadàbọ̀ aya Gómìnà ló fòpin sí awuyewuye tó ti ń jà ràn-ìn-ràn-ìn pé ìjà tó wà láàárín gómìnà àti ìyàwó rè kò lè parí mọ́.

Ní bayi, tí ìjà ti pari ní pàtàkì jùlọ, tó ku nǹkan bii ọ̀ṣẹ̀ kan tí wọn yóò búra fún Gómìnà fún sáà kìíní olódindi yàtọ̀ sí àjẹkù ìjọba Àkétì tó ti ń bá bọ̀ tẹ́lẹ̀.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×