Ó mà ṣe ooo! Mọ̀lẹ́bí fi Mọ́jèlé pa Dókítà Lọ́jọ́ Ọdún.

Olóògbé Dókítà Tony

Bíi àgbàrá òjò ní omi ojú ṣe ń sàn loju àwọn ènìyàn Abúlé Nenu ní ìjọba ìbílẹ̀ Obingwa ní ìpínlẹ̀ Ábíá ní ọjọ́ kẹrindinlógbọ̀n osù Kejìlá ọdún yìí nígbà tí wón ṣàdédé.gbò ikú Dókítà Tony.

Ọ̀rẹ́minú Olóògbé Tony,Ọmọọba Agbara ló fi ojú ọ̀rọ̀ yìí léde nínú àtẹ̀jáde kan lórí ìtàkùn abẹ́yẹfò X rẹ̀. Ó sàlàyé síwájú pé Mọ̀lẹ́bí arákùnrin náà ló fi májèlé sínú ọtí arákùnrin yìí tó bá tí ì fi ń bì títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lára rẹ̀.Ó fi ìyàlẹ́nu rẹ̀ hàn sí ìwà aburú náà nítorí àwọn méjèèjì súnmọ́ ara wọn.

Ọ̀gbẹ́ni Agbara ní “Ọ̀kan lára àwọn Mọ̀lẹ́bí Tony ló fi Májèlé sínú ọtí rẹ̀.Ní kété tí ó sì ti ṣe iṣẹ́ ibi ti tán ló ti sá kúrò nínú Abúlé Nenu” Ó wá rọ àjọ Ọlọ́pàá láti ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà láti fi ojú aṣebi hàn.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×