Ó mà ṣe o! Tọkọtaya kú sínú ìjàm̀bà Kẹ̀kẹ́ Ní Àkúrẹ́

Pòròpòrò ni omijé ń bọ́  lójú àwọn ènìyàn ní òpópónà Ìdànrè ní ìlú Àkúrẹ́ lọ́jọ́ ẹtì látàrí ìjàm̀bá ọkọ̀ àjàgbé àti kẹ̀kẹ́ Márúwá tó mú ẹ̀mí tọkọtaya àti awakọ̀ Kẹ̀kẹ́ náà lọ.

Ọ̀rọ̀ di bóòlọ-o-yàgò nígbà tí Àjàgbé àti Kò Márúwá náà ti kọlu ara wọn tí ènìyàn mẹ́ta sì sọ ẹ̀mí nù lẹ́yẹ-ò-sọkà.

Óṣojú mi pàtó ní eré àsápajúdé ló ló ṣe okùnfà ìjàm̀bá náà.

Ní kété tí làlúrí náà ti ṣẹlẹ̀ ni awakọ̀ Tírélà náà ti fi ẹsẹ̀ fẹ nítorí ìbẹ̀rù àwọn ènìyàn tí inú ń bí.

Kò sí pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn náà tó ṣe fi ara hàn ní àgọ́ ọlọ́pàá B Division,Òkè-Àró, Àkúrẹ́.Bó ti dé ibẹ̀ ni àwọn èrò ya lu àgọ́ ọlọ́pàá náà tí wọ́n si ń ju òkúta sí ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá.

Àwọn Ọlọ́pàá náà dá wọn lóhùn pèlú ibọn tajútajú.Eléyìí fa àkọlùkọgbà tí àwọn ọlọ́pàá sì ń he àwọn ènìyàn àti Márúwá.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×