
Gbajúgbajà Olórin ṣèwọ́ṣèwọ́ ti ẹnu kìí sìn lára rẹ̀ bíi Afọ́ìkéèmù nnì,Abeeb Òkìkíọlá tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Pọ́tébù ni ilé ẹjọ́ Májísìréètì kan ní ìlú Ifọ̀ ti fi kobíowú wọn ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta tòhun ti iṣẹ́ àṣekára fún báyìí.
Nígbà tó ń ka ìdájọ́ rẹ̀, Adájọ́ Babájídé Ìlò ní inú oṣù kẹta ni Olórin náà ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀hún nígbà tí ọ̀gá Ọlọ́pàá Rìpẹ́tọ̀ Hammed Moshood kó àwon ọlọ́pàá kan ṣòdí láti fi páḿpẹ́ òfin mú Pọ́tébù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kan (tí gbogbo wọn tí júbà ehoro báyìí) tó sì takú wọǹle tó bẹ́ẹ̀ tó fi gba ẹ̀jẹ̀ lára Rìpẹ́tọ̀ Hammed Moshood ní ilé ọtí Odogwu tó wà ní Òkè Ọ̀sà ní Ìlógbò.
Gẹ́gẹ́ bó ti wí, ìhùwàsí yìí jọ ti ẹranko, ó sì tako Abala kẹrin ẹsẹ kìíní ìwé òfin ìjọba ìpínlẹ̀ ògùn tí wọ́n ṣe àtúnṣe rẹ̀ ní ọdún 2017.
Gẹ́gẹ́ bíi Gbajúgbajà láwùjọ, wọ́n gba béèlì rẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún ṣùgbọ́n,ó hùwà àbùkù láìyọjú sí ilé ẹjọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n wá ń wà kiri kí ọwọ́ tó tẹ̀ ẹ́ ti wọ́n sì fi í sí gáló láti ọjọ́ Ọjọ́bọ tó kọjá di ọjọ́ ìṣẹ́gun ọ̀ṣẹ̀ yìí.
Nínú ìdájọ rẹ̀, ó ní ìwà Pọ́tébù tako abala kẹtàdínnígba òfin Ọ̀daràn ti ìpínlẹ̀ Ògùn ti ọdún 2006.
Ó wá rán an lẹ́wọ̀n oṣù mẹ́ta pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára tàbi kó san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
