ÒṢEMÀWÉ DI OLÓRÍ FÁSITÌ Ẹ̀KỌ́ṢẸ́ ÌṢÈGÙN

Ọba Dókítà Kíladéjọ

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oǹdó, Lucky Orímisàn Aiyédàtiwa ti yan Òṣemàwé ti ìlú Oǹdó, Ọba Dókítà Victor Kíladéjọ,Jílò Kẹta gẹ́gẹ́ bíi Olórí ilé Fásitì Ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìṣègùn tí a mọ̀ sí UNIMED tó wà ní ìlú Oǹdó.

Gómìnà ní èròngbà ìyànsípò yìí ni láti tún ilé ìwé náà sọ bíi ẹní ṣọgbá.Ó tẹ̀ síwájú pé ìrírí Kábíyèsí gẹ́gẹ́ bíi Onísègùn Òyìnbó yóò wúlò púpọ̀ láti sọ ilé ìwé náà di àpèwááwò láàrin àwon akẹgbẹ́ rẹ̀ yíká àgbáyé.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×