Nítorí Pé Wọ́n jí Pọ̀nmọ̀; Ilé-ẹjọ́ rán tọ̀mọ-tìyá lẹ́wọ̀n

Adájọ́ Odùmóṣù tí ilé ẹjọ́ Májísìréètì tó wà ní Àgọ́ Òkò ní Abẹ́òkúta ti fi kobíowú wọn ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta fún ìkọ̀ọ̀kan Abilékọ Fàlílátù Amidu àti ọmọ rẹ̀ Ayìsátù Amidu lórí ẹ̀ṣùn pé wọ́n jí ṣakaṣaka tó kún fún pọ̀nmọ́ gbígbẹ,ẹja àti ẹran tìǹkó tà léyìn tí wọ́n gbé sá lọ.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tó Naijanotes yorùbá létí, Arábìnrin Kàfáyátù Àlàó ló fẹjọ́ sùn pé òun gbé ṣakaṣaka tó kún fún pọ̀nmọ́ gbígbẹ, ẹja àti ẹran kí ó bá òun gbée lọ sí sọ́ọ̀bù ṣugbọn tí Fàlílátù àti ẹrù náà pòórá kò tó di pé àwọn ọlọ́pàá ṣe àwárí rẹ̀ lẹ́yìn tí òun fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ wọn.

Agbẹnusọ fún ìjọ̀ba,Rìpẹ́tọ̀ Kẹ́hìndé Fáwùnmí sàlàyé ní ilé ẹjọ́ pé  Fàlílátù Amidu gbé ẹrù náà fún ọmọ rẹ̀ Ayìsátù Amidu láti jíi gbé sá lọ láti tà á.Eleyii túmọ̀ sí pé olè ni arábìnrin náà jà.

Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà, Adájọ́ Odùmóṣù wá pàṣẹ kí tìyá-tọmọ náà máa lọ gba atégùn ní ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ọdún mẹ́ta tàbí kí wọ́n san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún márùn-ún ẹnìkọ̀kan wọn.Kí wọ́n tó san owó ìtanràn náà,wọ́n ní láti kọ́kọ́ san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ẹnìkọ̀kan.Àìjẹ́ bẹ́è, kí wọ́n lọ lo sáà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×