Nítorí pé Ó sùnta:Kóòtù Pàṣẹ kí wọn na ìyàwó ilé bí ẹní lu bàrà

Ìyà tí ìyàwó ilé kan jẹ látàrí pé ó kọ̀ kò sunlé ju tí Màálù tó kángun sí Fúlàní lọ lọ́ṣẹ̀ tó kọjá lọ .

Ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ nílẹ̀ Afghanistan ló da’jọ pé kí wọn ó já Obìnrin náà sí ìhòòhò kí wọ́n sì to ọgbọ̀n ẹgba sí í ní Akinyemi ara, kí ó sì tún lọ fi ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà jura pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára.

Látí ìgbà tí Taliban ti gba ìjọba ilẹ̀ Afghanistan ní wọ́n ti ń ṣe àmúlò àwọn òfin kàn-án-nípá ọlọ́kan-ò-jọ̀kan lórí àwọn ènìyàn ìlú náà.Kódà, àjọ Ìṣọ̀kan àgbáyé ti a mọ̀ sí United Nation ti kìlọ fún orile-ede náà ṣùgbọ́n wọ́n fi ààké kọ́rí.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ti lùgbàdì òfin ilẹ̀ yii tó ti já sí ikú fún àti orísirísi ijiya miiran.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×