
Gbajúgbajà òṣìṣẹ́ tíátà tó ní ẹ̀bùn àìmọye nnì, Ibrahim Chatta ti lahùn síta láìfòlò fọhùn pé lóòótọ́ ni ìlú le àti pé oko tó ń jágún kò jágún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Nàìjíríà mọ́.Lórí ẹ̀rọ ayélujára Instagram rẹ̀ ló ti fojú ọ̀rọ̀ yìí léde ní ọ̀ṣẹ̀ tó kọjá.
Chatta sàlàyé pé òun kò jẹ àwọn Òṣìṣẹ́ òun lówó rí ṣugbọn lọ́wọ́ tí a wà yìí, owó oṣù mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni òun jẹ wọ́n nítorí pé nǹkan le.Ó ní òun kò sọ èyí nítorí kí àwọn èèyàn lè ran òun lọ́wọ́ bí-kò-ṣe-pé kí ìjọba lè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣe àdá, kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ tó tọ́ láti mú kí ará lè tu ará ìlú tó dìbò fún wọn.
Onítíátà tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Bacita ní ìpínlẹ̀ Kwara náà tẹ̀ síwájú pé kìí ṣe pé òun ni ẹ̀nìkankan lọ́kàn tàbí pé àwọn kan ni ọ bẹ òun níṣẹ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí òun ń sọ.Nítorí náà, kí ẹnìkankan má ṣe fí ojú òṣèlú wò ó tabi fi etí òdì gbọ́ ọ.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní kò yẹ kí àwọn òṣeré Nàìjíríà máa rùnpà rárá pẹ̀lú ẹ̀bùn tí wọ́n ní ṣùgbọ́n àìṣedéédé àwọn olórí wa ló ń kó ìnira bá ẹ̀ka gbogbo.Fún àpẹrẹ, ó ní ìjọba Goodluck Jonathan ya owó tùùlùtuulu kan ṣọ́tọ́ fún àwọn onítíátà tó bá nílò ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n etí tí obìnrin fi ń gbóhùn orò ní ọ̀rọ̀ ọ̀hún láti ìgbà náà títí di àsìkò yìí.
Ó wá rọ gbogbo awọn olóṣèlú láti máa fi òtítọ inú àti ìbẹ̀rù Elédùmarè ṣe ìjọba nítorí kò sí ohun tí a mú wá ayé kò sí sí ohun tí a ó mú padà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
