Nítorí ikú tó Pa Ọlọ́pàá Blessing Yusuf: Àwọn Ọ̀dọ́ Na Ọ̀gá Ọlọ́pàá Ní Àlùpamópòó.

Bí àwọn ọlọ́pàá tó gbé òkú ọ̀kan lára wọn, Blessing Yusuf Suleiman tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Ọmọ Alhaja lọ sí ilé rẹ̀ ní Osí ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Àkúrẹ́ bá ṣàfira ni, òkú kì bá di púpọ̀ látàrí bí àwọn ọ̀dọ̀ agbègbè náà ṣe síná ìyà bolẹ̀ fún wọn tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò fi rántí gbé mọ́tò tí wọn gbé wá padà lọ.

Ẹni orí yọ ó dilé ni ọ̀rọ̀ dá nígbà tí wọ́n he ọ̀gá ọlọ́pàá tó kó wọn ṣòdí wá tí wọ́n sì ń gbá a lójú-nímú bíi kẹríkẹrì.Bí òun náà ṣe ja àjàbọ́ lọ́wọ́ wọn báyìí ni gìgísẹ̀ tìrẹ̀ náà ń kàn án ní ìpàkọ́.

Gẹ́gẹ́ bi a ti gbọ́, ìyàwó olóògbé ló pe ọkọ rẹ̀ nígbà tí kò gbúròó rẹ̀ fún wákàtí mẹ́rìnlèlógún . Ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ kàn dún lásán ni;ẹnìkankan kò gbe.Lẹ́hìn wákàtí kan ni ọ̀gá Ọlọ́pàá ibi ti ọkọ rẹ̀ ti ń ṣe iṣẹ́ tí a mọ̀ sí DPO pè padà tó sì túfọ̀ fún un pé ọkọ rẹ̀ ri sí inú odò,ó sì ti jẹ́ ìpè Ẹlẹdàá àti pé wọ́n ń gbé òkú rẹ̀ bọ̀ ní ọjọ́ kejì.

Nígbà tó di ọjọ́ kejì gẹ́gẹ́ bi ẹ̀jẹ́ wọn,wọ́n gbé òkú Blessing dé nínú pósí tí wọ́n ti kàn pa. Àwọn ọ̀dọ́ agbègbè ibẹ̀ wá takú pé àwọn fẹ rí òkú tí wọ́n gbé wá ki àwọn tó yọ̀ǹda wọn.Sí ìyàlẹ́nu wọn,iná ló jó Blessing gúdúgúdú.

Èèmọ̀ kín ni irú èyí? Ǹjẹ́ ẹ wá ṣàlàyé ìdí tí òkú tí omi pa ṣe jóná teyínteyín ni àwọn ọlọ́pàá bá fi akẹtẹ bà á láìnááni ọkọ̀ tí wọ́n gbé wá.Ìdí nìyii tí wọ́n fi rọ̀jò ìyà lé ọ̀gá wọn lórí kí òun náà tó ja àjàbọ́ lọ́wọ́ wọn.

Ọ̀rọ̀ tó gba ẹnu àwọn ènìyàn kan ni pé bí ọlọ́pàá bá le hu ìwà àìlódodo báyìí sí ara wọn,mélòómélóó wá ni ti ará ìlú?

Alukoro àjọ Ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Oǹdó, Arábìnrin Fúnmiláyọ̀ Ọdúnlámì sì ti fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ pé àwọn yóò ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×