Nítorí ikú ọmọ ọmọ Ọmọ́gẹ̀; alága ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa fòfin de àwọn Sarin-sagolo(Scavengers) ní ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa

Alága ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa, Họnọrèbù Andrew Ògúnṣakin ti fòfin de àwọn Sarin-sagolo ti a mọ̀ sí Scavengers ní ìjọba ìbílẹ̀ rẹ

Ohun tó fa òfin pajawiri yìí ní bí ọ̀kan lára àwọn Sarin-sagolo ti a mọ̀ sí Scavengers ṣe fi ọ̀bẹ gún ọmọ ọba Ogooluwa Ọmọ́gẹ̀ tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọmọ gbajúgbajà olórin bírípo tó ti dì olóògbé nnì, Comfort Omoge pa lórí ọ̀rọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀.

Ògúnṣakin ní ó ń bọ̀,ó ń bọ̀, àwọn la ń dẹ dè é, láyé àtijó ni, ṣùgbọ́n ojú la ń mú tó o báyii.Bi ìjọba kò bá tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi sàdá ní kíákíá, Igi imú ẹlẹ́dẹ̀ kò ní pẹ́ tí yóò fi wọ ọgbà.

Ó wá pàṣẹ fún gbogbo àwọn agbófinró ní ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa láti mú òfin náà ṣẹ nípa ríríi dájú pé ẹni yòówù tó bá taṣẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ jó lamba níwájú òfin.

Alága ìjọba ìbílẹ̀ Òkìtìpupa wá rọ àwọn ènìyàn ìjọba ìbílẹ̀ náà kí wọ́n ó b’omi sùúrù mu kí kóówá sí máa bá iṣẹ òòjọ́ rẹ̀ lọ láìsí ìfòyà tàbí ìbẹ̀rù kankan

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×