
Àwọn Ọkùnrin Amòòkùnsèkà Méjì kan, Abubakar Ibrahim àti Isah Ayuba ti ń ṣẹ́jú pàkò bíi Mọ́námọ́ná látìmọ́lé látàrí bí wọ́n ṣe gba ẹ̀mí Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Felicia Namkywa nitori kí ọ̀kan lára wọn, ìyẹn, Abubakar Ibrahim má baà san Ẹgbẹ̀rún lọ́ná ogójì náírà to jẹ Olóògbé ọ̀hún. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Obi ní ìpínlẹ̀ Nasarawa.
Alukoro ileese Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Nasarawa,Ọ̀gá ọlọ́pàá Rahman Namsel ló fojú ọ̀rọ̀ yìí léde nígbà tí ó ń bá Àgbáríjọ àwọn Oníròyìn sọ̀rọ̀ ní ìlú Lafia.
Gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, ọgbọ́n ẹ̀wé ni Abubakar Ibrahim fi tan Felicia Namkywa lọ sí Gàhá Fúlàní pé kó wá ra àwọn ohun erè oko oníhóró kó tó di pé ó tàn án lọ sí inú igbó kìjíkìjí kan níbi tí Óun ati Ayuba ọ̀rẹ́ rẹ ti pa á,wọ́n jí owó tó tò Ẹgbẹ̀rún lọ́ná okòólèlẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà (₦520,000:00)Lẹ́hìn èyí ni wọ́n ju òkú ti sí inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ kan .
Abúlé Shember lẹ́gbẹ̀ẹ́ Agwatachi lágbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Obi ní ìpínlẹ̀ Nasarawa ni àwọn Ọ̀daràn ẹyẹ tó n mú ọsàn yìí tí wá.Wọ́n sì ti jẹ́wọ́ pé lóòótọ́ ní àwọn dá ọ̀ràn náà.
Ọgá Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Nasarawa,Umar Sheu Nadada ti wá pàṣẹ kí wọ́n fojú àwọn Aláìláàánú ẹdá ba ilé ẹjọ lẹ́yẹòsọ́kà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
