.

Ìrètí pípẹ́ a máa ṣe ọkàn ní àmódi.Ìgbà ara sì là ń búra,ẹnìkan kìí bú Ṣàngó ní inú ẹ̀ẹ̀rùn.Inú oṣù keje ọdún tó kọjá lọ ni Ààrẹ Tinúbú tí buwọ́ lu owó oṣù titun fún àwọn òṣìṣẹ́ yíká ilẹ̀ Nàìjíríà.
Ohun tó wá jẹ́ ìyàlẹ́nu jùlọ ní pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Àpapọ̀ gan-an ni kò tí ì gbọ́ ‘Mó kò ó’ owó oṣù titun náà títí di àsìkò yìí.Yíò dára,yí ò dára tí arúgbó fi ń kú tòhuntòsì ni ọ̀rọ̀ náà wà ní àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ kan titi di àsìkò yìí.
Ó wá yẹ ẹni gbogbo kó dín owó aró, kò yẹ Atọ̀ọ́lé, tàbí nígbà tí iná bá ti ilé Ọ̀ṣanyìn jó wá;níbo láti fẹ́ mú òògùn sà?
Kò tọ́ kò yẹ kó jẹ́ pé ilé iṣẹ ìjọba àpapọ̀ ni kò ní san owó oṣù titun titi di àsìkò yìí pẹ̀lú bí ohun gbogbo ṣe gbówó lérí gegege.
Fún àpẹẹrẹ, ilé iṣẹ́ Aṣèdánwò NECO wà lára àwọn ilé iṣẹ tí kò tíì rí owó oṣù titun gbà.Ifọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú òṣìṣẹ́ wọn kan tí a forúkọ bò lásìírí jẹ́ ká mọ pé owó oṣù àtijọ ni àwọn sì ń gbà di àsìkò yìí.
Bâkan náà lọmọ ṣorí ní àwọn ilé iṣẹ bíi ọ̀rọ̀ abẹ́lé, Ìgbáyégbádùn ọmọnìyàn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Òṣìṣẹ́ kan nílé ise tó ń mójú tó bí wọ́n tí ń san owó oṣù òṣìṣẹ́ sọ ní tirẹ̀ pé pípẹ́ tó pẹ́ kí wọ́n tó buwọ́ lu ètò ìṣúná ọdún 2025 ló fa sábàbí.
Àjọ NLC àti TUC náà ṣẹ́ ẹsùn pé àwọn dá àwọn òṣìṣẹ́ dá wàhálà náà..Wọ́n ní rárá o ṣugbọn ọrọ náà yóò yanjú láìpẹ́.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
