Nínú Sọ́ọ̀sì Níbàdàn,Olè jí Màálù tí wọ́n fẹ́ fi ṣe Ìkórè tú lọ lórí ìṣo.

Bí àlá ló ṣe rí nílé ìjọsìn ìjọ Mímọ́ Kristi láti Ọ̀run wá ìyẹn ,Celestial Church of Christ,Testimony Parish,Elerumoke,Ẹgbẹ́dá, Ìyànà Àjíà, Ìbàdàn láìpẹ́ yìí ní bí ti àwọn olè,Alọkólóhunkígbe ti jí màálù gàgàrà méjì tí owó rẹ̀ tó mílíọ̀nù méjì náírà tí wọ́n ṣo mọ́lẹ̀ fún ìkórè ìjọ náà lọ.

Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ sàlàyé pé bí ẹní wá abẹ́rẹ́ ni àwọn ènìyàn ṣe ń wa Màálù méjèèjì nígbà tí wọ́n fẹ́ wọn kù lóri ìṣo.

Orí ìkànnì abẹ́yẹfò X ìjọ náà ní ọ̀rọ̀ náà ti lu jáde nígbà tí wòlíì àgbà ìjọ náà,Rótìmí Tèmítọ́pẹ́ Agúnbiade fi léde pé “Èyí ni láti kéde pé àwọn olè ti jí màálù gàgàrà méjì tí a ṣo mo láti pa fún ìkórè àgbà ti ọdún yìí lọ.Ẹnikeni tó bá bá wa ríi kó kàn sí wa”

Lóòótọ́ ni alàgbà fi adiresi àti fóònù sílẹ sùgbón kò sí ẹni tó gbọ́ “Mo kò ó”àwọn Màálù náà di àsìkò yìí

Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ijọ náà tó bá wa sọ̀rọ̀ lábẹ́ aṣọ ṣe àlàyé pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà fi òùntẹ̀ jàn-án pé lotiitọ́ àti lódodo, ìwà ìbàjẹ́ ti yọ yàrá yọ pálọ̀ sí ọkàn àwọn ọmọ Naijiria.

Ọmọ tuntun kìí ṣe àkọ́pa àjẹ́ ni ìhùwàsí tí tú Màálù lórí èèkàn ní agbègbè náà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×