Ní Orílẹ̀ -èdè Dominican,Àjà ilé fàájì jìn,Ó sì pa ogunlọ́gọ̀ ènìyàn.Nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ara pa

Làlúrí burúkú ló ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ ìṣẹ́gun ọ̀sẹ̀ yìí ní Santo Domingo ní orílẹ̀-èdè Dominican níbi tí àjà ilé fàájì kan ti jìn lásìkò tí gbájúmọ́ eléré kan tó ń jẹ́ Rubby àti àwọn ẹgbẹ́ Merengue artist rẹ̀ ti ń dá àwọn ènìyàn lára yá .

Kò dín ní ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn (300) tó wà ní inú gbọ̀ngàn fàájì yìí nígbà tí làlúrí náà ṣẹlẹ̀.Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn kú tí ogunlọ́gọ̀ sì fara pa.

Lára àwọn tó wà nínú ilé fàájì náà lásìkò tí àjà jìn ni àwọn ògbóhùntarìgì eléré ìdárayá tó tí gba àmì ẹ̀yẹ àgbáyé mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.Rubby tó ń ṣe eré lọ́wọ́ lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn.

Inú ilé fàájì náà rèé lẹ́yìn tí àjà jìn tán
Àwọn òṣìṣẹ́ ń gbìyànjú láti dóòlà àwọn tó wà nínú ilé náà
Wọ́n ń gbé òkú ẹnìkan jáde kúrò nínú gbọ̀ngàn náà
Àwọn ènìyàn ń ṣe ìwádìí láti mọ̀ bóyá ẹni wọn wà níbẹ̀
Ọ̀kan lára àwọn tó ṣòfò ẹ̀mí ni àwọn ènìyàn rí ń fi ọwọ́ kan fọ́tò rẹ̀ yìí
Ní ìta ilé fàájì níbi tí wọ́n ti ń rẹ ara wọn lẹ́kún
Omijé ń sàn bí odò lójú àwọn tí wọ́n pàdánù ẹni wọn

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×