Ní Òdìgbó;Pásítọ̀ fún Abirùn ọmọ Ọdún Mẹ́tàlàá lóyún

Kàyéfì ńlá ló jẹ́ fún àwọn ènìyàn ìlú Òkè Ìgbúròwò ní ìjọba ìbílẹ̀ Òdìgbò nígbà tí àríyànjiyàn sọ lórí ẹni pàtó tó fún ọmọbìnrin abirùn kan lóyún ní ìletò náà.

Ẹni tí wọ́n fura sí jùlọ ni Olùsọ́ àgùtàn Peter James ti ìjọ Àpọsítélì ti Jésù tó wà ní ìlú náà.

Nígbà tí wọ́n tọ́ka ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí gẹ́gẹ́ bíi ẹni tó loyún náà;kò jampata rárá ṣùgbọ́n lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ló wá yarí pé kìí ṣe òun mọ́.

Ìdí rèé tí wọ́n fi gbé Ọkùnrin Ajóḿbàdí Pásítọ̀ yìí lọ sí ilé ọlọ́jà ìlú náà,Ọlọ́jà Moses Ògúnmóyèwá.

Gbogbo akitiyan àwọn ènìyàn láti mú kí Pásítọ̀ yìí jẹ́wọ́ ló já sí pàbó.Àwọn kan ní ohun tó fà á tí Pásítọ̀ fi tún èrò rẹ̀ pa ni àbùkù tó wà lára ọmọbìnrin náà.

Ìyá ọmọbìnrin aboyún náà, Arábìnrin Victoria aya Benard ní àwọn ní ẹ̀rí tó dájú ṣáká pé Pásítọ̀ náà ló loyún arábìnrin náà nítorí ọ̀rọ̀ ìjẹ́wọ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ ń bẹ lọ́wọ́ àwọn.

Ó wá jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn kò ní gbà kí Pásítọ̀ kan sọ ọmọ awọn di olóríburúkú.

Nígbà tí a gbọ́ pé ọ̀rọ̀ náà ti dé olú ilé ìjọ náà tó wà ní ìlú Òdìgbó,a gbìyànjú láti bá Pásítọ̀ àgbà ibẹ̀ sọ̀rọ̀ sùgbón wọ́n kí láti dá ikọ̀ ìròyìn wa lóhùn.

Ẹ̀wẹ̀,ọ̀kan lára àwọn ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ Pásítọ̀ tí kò fẹ́ kí á dá orúkọ òun ní ìgbésẹ̀ tó lágbára ń bọ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà àti pé àwọn yóò máa kàn sí wa bí àkókò bá tó..

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×