Ní Oǹdó,Ọmọ́tọ́lá dèròo Kóòtù nitori pé ó ba mọ́tò onímọ́tò jẹ́.

Ọkùnrin ẹni ọdún márùndínláàádọ́ta(45yrs) kan,Ọmọ́tọ́lá Ọlálékan ló ti ń jó lamba níwájú òfin ní Kóòtù Májísìréètì ti ìlú Òdìgbó ní ìpínlẹ̀ Oǹdó bayii lórí ẹ̀ṣùn pé ó fínnúfíndọ̀ ba jíà ọkọ̀ Toyota corolla tó jẹ́ ti Ọ̀gbẹ́ni Àbáyọ̀mí Amusa tí owó rẹ̀ tó mílíọ̀nù kan ó lé òjìléláàádọ́rùn-ún náírà(₦1,940,000) jẹ́ láìbèṣùbẹ̀gbà.

Ọjọ́ keje, oṣù kẹrin ọdún yìí ní Ọ̀daràn ọ̀hún ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ náà ní Gáréèjì Benin ní ìlú Ọ̀rẹ̀.

Agbèfọ́ba Usifoh James tó wọ́ ẹjọ́ náà lọ síwájú Adájọ́ Festus Akinlolú ní ìwà tí Ọmọ́tọ́lá Ọlálékan hù náà tako àgbàlá ọ̀tàléerínwó ó dín mẹ́sàn -an,ẹka kẹtàdínlógójì  òfin Ọ̀daràn ti ìpínlẹ̀ Oǹdó ti ọdún 2006.

Ó wá rọ ilé ẹjọ́ kó fún òhun ní àsìkò dírẹ̀ láti gbé ẹ̀ṣùn náà yẹ̀wò dáradára kí òun sì le mú àwọn ẹlẹrìí wá.

Agbẹjọ́rò olùjẹ́jọ́, Amofin M.E Tiewa kò tako ẹ̀bẹ̀ ọgbẹ́ni Usifoh James ṣùgbọ́n ó bẹ adájọ́ kó fún oníbàárà òun ní ànfààní béèlì tí kò gunpá.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Adájọ́ Festus Akinlolú gba béèlì  Ọmọ́tọ́lá pẹ̀lú mílíọ̀nù kan àti onídùúro méjì

Ó wá sún ìgbẹ́jọ́ síwájú da ọjọ́ kẹfà oṣù karùn-ún ọdún yìí.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×