Ní Oǹdó, Ọ̀nà Oǹdó sí Ọ̀rẹ̀ di; Àwọn Ọkọ̀ wà lójú kan náà fún Wákàtí Mẹ́rin

Bẹ́rẹ́kẹ́tẹ́ ni ọ̀nà Oǹdó sí Ọ̀rẹ̀ dí ní ìlú kan tí wọ́n ń pè ní Ajùẹ́ ní òwúrọ̀ òní ọjọ́ ìṣẹ́gun ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ọdún yìí tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi sí lílọ-bíbọ̀ ọkọ̀ láti Oǹdó sí Ọ̀rẹ́ láti nǹkan bíi agogo méje òwúrò di agogo méjìlàá ọ̀sán.

Ohun tó fa sábàbí ni ojú ọ̀nà tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ tí kò ṣe í gbà fún àwọn onímọ́tò.Ojú ọ̀nà eléruku tí wọ́n pèsè fún àwọn awakọ̀ láti máa rin ń yọ̀ ni bàlà bí ilá,eleyii tó sì fa kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀, pàápàá jùlọ àwọn Àjàgbé eléjò kó máa rì sínú ẹrọ̀fọ̀ tí àrọ̀ìrọ̀dá òjò dá sí ojú ònà náà tó sì fa súnkẹrẹfàkẹrẹ mọ́tò lójú ọ̀nà tí kò ní ọ̀nà ẹ̀bùrú náà .

Ohun tó tún túbọ̀ pa kún wàhálà náà ni ti òjò tó tún bẹ̀rẹ̀ sí ní rọ̀, tó sì sọ akitiyan àwọn àtọ́nàṣe tó ń gbìyànjú àtúnṣe ojú ònà fún àwọn mọ́tò tó ti há di òtúbáńtẹ́.

Agogo méjìlá kọjá kó tó di pé ojú ònà náà là dírẹ̀ fún àwọn onimọ́tò láti kọjá.ó kéré tán, wákàtí mẹ́ta sí mẹ́rin ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ èniyàn fi rin Ọ̀rẹ̀ sí Oǹdó ti kò tó ìrìn wákàtí kan.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×