
Ìjà ààlà ìlẹ̀ ti gbẹ̀mí ẹnìkan tí wọ́n sì tiná bọ odidi ilé mẹ́sàn-án ní Àágba ní ìjọba ìbílẹ̀ Sùúrùlérè ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ìyá àgbà Racheal Bámidélé tó ti lé ní ẹni àádọ́rin ọdún ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn.
Àjọ Ọlọ́pàá ipinlẹ Ọ̀yọ́ sì ti fi páḿpẹ́ ọba mú ọ̀kan lára àwọn Afurasí tó hùwà ibi náà.orúkọ rẹ̀ ni Salaudeen Ismail.Ọmọ bíbí ìlú Òkò ní, ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n sì ni pẹ̀lú.
Alukoro àjọ Ọlọ́pàá ipinlẹ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Wálé Òsífẹ̀sọ̀ ní àmọ̀ímọ̀se ni ìwà ìbàjẹ́ náà nitori gbogbo àwọn tí wọ́n jó ilé wọn ni àwọn tó ń kó ipa kan tàbí òmíràn nínú ẹjọ́ ilẹ̀ tí wọ́n ń jà sí ọ̀hún tí ó wà ní Kóòtù lọ́wọ́lọ́wọ́.Ẹni kúkúrú wọlé,eégún kúkúrú jáde,taa ní kò ṣàìmọ̀ pé ẹni tó wọlé ló gbé agọ̀ wọ̀.
Ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹrin ní àwọn ènìyàn kan ya wọ ìlú Àágba tí wọ́n sì ń lu àwọn ènìyàn ní àlùpamópòó tí wọ́n sì tún ti iná bọlé àwọn èèkàn ìlú náà.
Ọ̀gá Ọlọ́pàá ipinlẹ Ọ̀yọ́,Johnson Adémọ́lá wáá ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti gbowúro ṣójú àwọn tí aje ọ̀rọ̀ náà bá sí mọ́ lórí.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
