Ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun,Oyin ta Àgbẹ̀ kan pa nínú oko rẹ̀.

Ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu ni ọjọ́ jímọ̀ ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹrin ọdún yìí jẹ́ fún àwọn ènìyàn ìdílé Alálàádé ní ìlú Adà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

Ohun tó fa sábàbí ni ìṣẹ̀lẹ̀ abàmì tó mú ẹ̀mí Abideen Ọlábíyìí lọ, tó sì sọ Solomon Kingsley àti Olóyè Olúṣẹ́gun Alálàádé di èrò họsibítù.

Oko wọn tó wà ní Ọlọ́bẹ̀ ní Ìgbájọ ni wọ́n lọ tí wọ́n sì ko àgbákò oyin tó ta wọ́n títí tí Abideen fi di èrò ọ̀run lójijì ti àwọn méjì yòókù kò sì mọra mọ tí wọ́n fi di èrò họsibítù.

Àgọ́ ọlọ́pàá ìlú Ọ̀tan Ayégbajú ló fi ìròyìn náà léde ní ọ̀sán àná sátidé ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù yìí.

Àgọ́ ọlọ́pàá Ọ̀tan Ayégbajú fi léde pé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Babásanjọ́ Alálàádé ló wá sọ ní ọ̀dọ̀ àwọn pé àwọn mọ̀lẹ́bí òun mẹ́ta ló lọ sí oko,oyin ta wọ́n, ọ̀kan kú, méjì dèrò ilé ìwádìí sì fi hàn pé bó ti wí gẹ́lẹ́ ló rí.

Wọ́n ti gbé òkú Abideen Ọlábíyìí tó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà sí ilé ìgbókùúsí Healthy Paradise Mortuary tó wà ní Ìkìrun fún àyẹ̀wò tó péye nígbà tí àwọn tó fara pa ń gba ìtọ́jú ní họsibítù.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×