NÍ ÌPÍNLẸ̀ OǸDÓ,ÌJÀM̀BÁ MỌ́TÒ GBẸ̀MÍ ÒṢÌṢẸ́ ÌJỌBA KAN,NÍGBÀ TÍ ÀWỌN METÀDÍNLÓGÚN MÓRÍ BỌ́

Ọjọ́ burúkú Èṣù gbomi mu ni ọjọ́ Sátidé ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹwàá ọdún yìí ní bí ìjàm̀bá mọ́tò ti gba ẹ̀mí ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ile-ise to ń bójú tó ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí a mọ̀ sí SUBEB ní ìpínlẹ̀ Oǹdó.Ikú ọ̀hún sí fìlà lórí àwọn mẹ́tàdínlógún yòókù .

Gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́,ibi ayẹyẹ ìsìnkú ìyá ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ náà ni wọ́n ń lọ  nígbà tí làlúrí náà ṣẹlẹ̀

Wón ti kó àwọn tó fara pa ninu ìjàm̀bá mọ́tò náà lọ sí ẹ̀ka ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ilé ìwòsan ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìṣègùn ti UNIMED tó wà ní ìlú Àkúrẹ́.

Bí ilé ìwòsan náà ti ń pèsè itóju fún àwọn tó fara pa ni wón sì ti gbé olóògbé tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sí ilé ìgbókùúsí ti ile iwosan náà.Kódà,wọ́n ti yọ̀ǹda àwọn tó fara pa niwọ̀nba.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×