Wọ́n jí Tọ́pẹ́ gbé lỌ́wọ̀,wọ́n ní kí ẹbí rẹ̀ ó mú ogún mílíọ̀nù wá.
Ará ìlú ń sá kíjokíjo.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé ti mú kí ìpínlẹ̀ Oǹdó ṣòro í gbé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ń di kànlekànle púpọ̀ jù.Àwọ̀n agbègbè bíi Àbòaṣakin,Ìlú-Àbò,Àgọ́ Páànù àtí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibòmíràn ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Àkúrẹ́ kò lè sún àsùnforílésùkà mọ́.Bí-ó-tilẹ̀-jẹ́-pé ìjọba ń fi ìgbà gbogbo sọ pé òun kájú rẹ̀,síbẹ̀ awọ kò ì tíì kájú ìlù nitori kàkà kí ewé àgbọn rọ̀,kokoko ló ń le.
Afẹ́fẹ́ ìjínigbé náà ti fa dé ìlú Ọ̀wọ̀ báyìí ní bí wọ́n ti jí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Tọ́pẹ́ Fàájì àti ìdílé rẹ gbé ní ilé wọn tó wà ní ọ̀nà ìpelè ní ìlú Ọ̀wọ̀ .
Sọ́ọ̀bù ni àwọn ẹní ẹlẹ́ni ti ń bọ̀ tí wọ́n dé iwájú ilé wọn.Kí wọ́n sì kale kí wọ́n sí géètì wọlé ni won bá jẹ wọ́n bíi ẹní he ìgbín.ọmọ wọn kan tó já àjàbọ́ lọ́wọ́ wọn ló fi tó awọn mọ̀lẹ́bí létí.
Àwọn Ajínigbé náà kọ́kọ́ sọ pé Ọgbọ̀n mílíọ̀nù náírà ni àwọn yóò gbà, ṣùgbọ́n wọ́n ti dín kù sí okòó mílíọ̀nù náírà báyìí.
Alukoro àjọ Ọlọ́pàá ipinlẹ Oǹdó.Abilekọ Fúnmiláyọ̀ Ọdúnlámì ni ọ̀rọ̀ náà kò ì tíì fé etíìgbọ́ àwọn. Ohun

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
