
Àwọn ará ìlú Ìgbàrà-òkè tíì ṣe olú ìlú ìjọba ìbílẹ̀ Ìfẹ́dọ̀rẹ́ ní ìpínlẹ̀ Oǹdó tú jáde sí àwọn òpópónà tó wà ní ìlú náà ní òpin ọ̀ṣẹ̀ yìí láti fi ẹ̀hónù hàn tako ọ̀gá ọlọ́pàá ìlú náà Ọ̀gbẹ́ni Gàníyù Dáwódù lórí ìwà ìbàjẹ́ lọ́kan-ò-jọ̀kan bíi ká gbé àre fún ẹlẹ́bi nítori owó, ká lọ́ni lọ́wọ́ gbà, ká tún ṣe agbódegbà fún olè àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Bí a bá lé ewúrẹ títí tí ó bá kan ògiri, yóò pa ojú dà báni jà.Idi rèé tí àwọn ẹgbẹ́ awakọ̀ ṣe tẹ́ pẹpẹ ìfẹ̀hónú hàn yíká tìbú-tòòró ilú náa pẹ̀lú orísirísi pátákó àkọlé bíi: olè ni DPO,Ẹ bá wa gbé Dáwódù kúrò abbl. Bí wón ti ń se èyí ni wọ́n tún ń kọ orisirisi orin bíi:DPO Olè! Dáwódù olè!
Nígbà tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, Ọ̀gbẹ́ni Owóẹ̀yẹ Máyọ̀wá tó léwájú àwọn afẹ̀hónúhàn náà ní ohun tí àwọn fẹ́ ní kí wọ́n bá àwọn gbé DPO náà kúrò ní ìlú àwọn nitori àwọn ìwà ìbàjẹ́ tó ń hù.
Ó júwe ìwà kí á máa lọ́ni lọ́wọ́ gbà lórí ọ̀rọ̀ yòówù tó bá ti dé iwájú ọgá olópàá náà.Wọ́n ní owó tó máa ń gbà bẹ̀rẹ̀ láti ẹgbẹ̀rùn lọ́nà igba sí mílíọ̀nù kan náírà.
Yàtọ̀ sí ìwà yìí,a tún máa kọ́ ará ìlú sí ara wọn pẹ̀lú ète àti gba owó.
Wọ́n wá rọ ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlè Oǹdó, Ọ̀gbẹ́ni Wilfred Afọlábí kó bá àwọn gbé Ọkùnrin náà kúrò lọ́dọ̀ àwọn kó máa baà ba ìlú jẹ́

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
