
Òjò àrọ̀ìrọ̀dá kan tó ti lọ́jọ́ ọdún ìtúnu àwẹ̀ tó kọjá yìí ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn dì aláìnílé lórí mọ ní ìlú Ògélè ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Asà ni ipinlẹ̀ Kwara.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ilé ìwé bíi Nawal-ud-deen Primary School, Community Grammar school àti ilé ìwòsan Alábọ́ọ́dé Health Care Centre tó wà ní ìlú náà ló fara kááṣá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàm̀bá atẹ́gùn náà.

Lárá àwọn ibi pàtàkì tó tún lùgbàdì ìjì náà ni Ààfin ọba ìlú náà, Alhadji Abubakar Àkànbí.Kódà,òpó wàyá tó gbé iná kọjá lọ sí Àfọ̀n láti Ògélè ti já pútupùtu tí àwọn ìlú náà sì ti wà ní òkùnkùn rabidun.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Alága Ẹgbẹ́ Ìdàgbàsókè ìlú Ògélè rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba kó má ṣe wo awọn níran.
Ọba Alhadji Abubakar Àkànbí náà kò sàìrọ Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara,Ọlọ́lá Abdurazak láti jòwó ran ìlú ọ̀hún lọ́wọ́
,

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
