
Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta Sheriff Oborevwori lórí ọ̀rọ̀ òkòwò àti ọjà tó ń lọ sílẹ̀ òkèèrè Arábìnrin Shimite Wilfred Bello ló ti rí ikú rẹ̀ he ní òwúrọ̀ òní ọjọ́ ajé ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹrin ọdún yìí ní ilé rẹ̀.
Kókó ohun tó pa arabinrin náà kò ì tíì hànde,ṣùgbọ́n ó jọ gáté kò jọ gàté,ó fi ẹsẹ̀ méjèèjì tiro gátegàte .Ọkọ Arábìnrin náà ní ẹni àfurasí jù nítorí ìjà àjakudorogbo ti wọ́n máa ń jà.
Harrison Gwamirishi tíí ṣe Olùbádámọ̀ràn sí Gómìnà lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn kéde ikú Bello lórí ìkànnì Facebook rẹ̀.
Victor Orijie naa kéde ikú rẹ pé ‘Ó ga oo!àfi ìgbà tí wọ́n pa Arábìnrin yìí.Ṣé tipátipá ni ọkọ tàbi ìyàwó fífẹ́ ní?
Oge Okonkwo ní tirẹ̀ ní ‘Àjọ ọlọ́pàá ti mú ọ̀daràn apàyàwó jayé náà ‘
Pẹ̀lú gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ó túmọ̀ sí pé ọkọ Arábìnrin náà lo júwe ọ̀nà ọ̀run fún un.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
