
Ilẹ̀ Namibia ti yan Ààrẹ àkọ́kọ́ lóbìnrin.Onítọ̀hún ni Abilékọ Netumbo Nandi Ndaitwah tí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ mọ̀ sí NNN.Ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú South West African Peoples Organisation (SWAPO) ní i ṣe.Láti ìgbà tí ilẹ̀ náà ti di ilẹ̀ olómìnira ní ọdún 1990 ló ti wà ní ìjọba.Òun sì ni ìgbákejì Ààrẹ ilẹ̀ náà titi tó fi di Ààrẹ.
Ọmọ ilé mọ́kànléláàádọ́ta ni ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ ní nínú ọmọ ilé mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún.Eléyii túmọ̀ sí ìdá mẹ́tàléláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àpapọ̀ gbogbo àwọn ọmọ ilé.
Ẹgbẹ́ òṣèlú Independent Patriotic for change (IPC) ló tún gbìyànjú tó ní ogun nínú àwọn ọmọ ilé eléyìí ló sì fi òpin sí awuyewuye tó ti ń lọ yíká ìlẹ̀ náà pé ẹgbẹ́ òṣèlú SWAPO ti tẹ́ àtí pé kò lè jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò náà.Ọdẹ́ SWAPO ti pa ògìdán sí oko, ojú ti babaláwo tó ní ọdẹ yóò pa eku.
Gẹ́gẹ́ bí obìnrin yìí ṣe jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tó jẹ Ààrẹ ní ìhà Gúsù Adúláwọ̀ ló sọ ọ́ di obìnrin kẹta tí yóò jẹ Ààrẹní ilẹ̀ Adúláwọ̀ lẹ́hin Ellen Sirleaf ti ilẹ̀ Liberia àtí Sania Hassan ti ilẹ̀ Tanzania.
Ẹ̀wẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú SWAPO ló ti fi àìdunnú wọn hàn sí iyànsípò Ndaitwah nitori wọ́n ní ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí ni wọ́n fi yan obinrin naa.
Ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú SWAPO kan tíì tún ṣe ọ̀jọ̀gbọ́n lẹ́ka tí wọ́n ti ń kọ́ni ní ìmọ̀ nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú ní ilé ìwé gíga julọ Pretoria University, Ọ̀jọ̀gbọ́n Henring Melber àwọn alágbára bíi mélòó kan tó wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú SWAPO ni wọ́n yan Ààrẹ láìfààyè sílẹ fún ẹlòmíràn láti díje tako Ndaitwah.
Ó sàlàyé pé ewu ńlá ni èyí jẹ́ fún ọjọ́ ọ̀la ìjọba tiwa-n-tiwa ní pàtó àti ètò òṣèlú ilẹ náà lápapọ̀.Ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú náà mìíràn tó ní kí wọn fi orúkọ bo òun lásìírí ní ètò ìdìbò abẹ́lé kankan kóò wáyé rárá àti pé tipátipá ni wọ́n fi yan obinrin náà lé àwọn lórí .Ó wá sọ pé ìjọba kàn-ànńpá àti ọwọ́ agbára ni ààrẹ fi dórí àlèéfà.
Ní báyìí,Ó mọ̀ í jó,kò mọ̀ í jó,alátàrí kẹ̀dìrì Ààrẹ Ndaitwah ti mú onílù wálé.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
