Ní Ìdànrè:Wèrè Gba Sọ́ọ̀bù Mọ́ Dọlápọ̀ Lọ́wọ́

Bí eré ori ìtàgé ló jọ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí ní ìlú Aládè -Ìdànrè níbi tí wèrè kan ti yà bàrá lọ sí sọ́ọ̀bù sìmẹ́ńtì kan tíí ṣe ti Arábìnrin Dọlápọ̀ Òlátúnjí tó sì kí arábìnrin náà mọ́lẹ̀.Bí kò bá sí àwọn ènìyàn tí wọ́n gba Dọlápọ̀ sílẹ̀, bóyá wèrè náà kì bá jẹ ẹran súnkunsí lára rẹ̀.Kí ojú má rí ibi, gbogbo ara lóògùn rẹ̀.Kíá,ó dìgbá-dagbọ̀n ó di ilé. Ó dájú pé yóò lò gbé igbá òpẹ́ pé Ọlọ́run kó òun yọ nínú ewu ni sọ́ọ̀sì rẹ̀ ní ọjọ́ àìkú tó bá tẹ̀lé ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Yorùbá bọ̀,wọ́n ní ‘Iná èsisi kìí jó’ni lẹ́ẹ̀mejì’ láti ìgbà tí orí ti kó Dámilọ́lá yọ lọ́wọ́ Aláágànnà ló ti ta kété sí sọ́ọ̀bù náà . Eléyìí sì ti kó òpùtà bá ọjà rẹ̀.Àbí taa ni yóò lọ ra ọjà níbí ti wèrè pàgọ́ sí?

Nínú ìfòròwánilénuwò tí Naija notes ṣè, ó hàn dájú gbangba pé ó tí tó ọjọ́ mẹ́ta tí Jáwéjura náà ti ń han àwọn ènìyàn agbègbè ibẹ̀ léǹmọ̀.Wọ́n ní ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn ló kọlu Mọ̀lẹ́bí àgbà olóyè kan ní ìlú náà.’Bi ìjọba kò bá tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi sàdá lórí ọ̀rọ̀ náà,àfàìmọ̀ kí Onígán-ángàn-àngán náà ó má pa ènìyàn’ Arábìnrin Mercy,ọ̀kan lára àwọn olùtàjà ni agbègbè ibẹ̀ ló sọ bẹ́ẹ̀.Nígbà tí ẹni ọ̀rọ̀ kàn,Arábìnrin Dọlápọ̀ Òlátúnjí ń ṣọ̀rọ̀,Ó rọ ìjọba ìbílẹ̀ Ìdànrè àti àjọ Ọlọ́pàá láti wá gba òun kúrò lọ́wọ́ ogun Aléniníṣọ̀ẹni tí wèrè dà sí òun lágbada.Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn agbègbè rẹ̀ fún bí wọ́n ti ṣúgbàá òun lásìkò ìkọlù náà.

Igbákejì alága ìjọba ìbílẹ̀ Ìdànrè sàlàyé pé etí ìjọba ìbílẹ̀ náà kò di sí jágbánrúju náà àti pé àwọn tí fí ọ̀rọ̀ náà tó àjọ Ọlọ́pàá ìlú Ìdànrè létí. Ó sì fi dá wa lójú pé àjọ Ọlọ́pàá yóò palẹ̀ ọmọkùnrin Ọlọ́dẹorí náà mọ́ lẹ́yẹ-ò-sòkà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×