
Gómìnà Adémọ́lá Adélékè ti ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti jáwé akìwọwọ fún àwọn ènìyàn Ifón,Ìlobùú àti Ẹ̀rìn-Ọ̀ṣun kí wọ́n ṣíwọ́ ogun àjàdijú tí wọ́n ń jà káàkiri;àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, òun yóò rọ àwọn ọba wọn lóyè ni nítorí àkúkú ì joyè sàn ju ẹnu mi kò kà ìlú lọ.
Adélékè fojú ọ̀rọ̀ yìí léde nígbà tó ń kéde bí ó ti dẹ okùn òfin kónílé-ó-gbélé òníwákàtí mẹ́rìnlélógún sílẹ̀ sí òníwákàtí méjìlá. Gómìnà ni òun gbọ́ pé àwọn Ajímùjẹ̀ ẹ̀dá kan ti tún ń gbìyànjú láti lo oore-ọ̀fẹ́ okùn kónílé-ó-gbélé tí òun dẹ̀ náà láti hùwa ibi, ṣùgbọ́n tí Ọ̀fọ́n-àn bá fìrù nagbá,imí ẹran yóò bọ́ nídìí ẹni yòówù tí aje ọ̀rọ̀ náà bá sí lé lórí láìwo bí onítọ̀hún ṣe gàǹgà-gongo tó láwùjọ.
Adélékè tẹ̀ síwájú pé òun kò lè la ojú sílè kí àwọn Kọ̀lọ̀rànsí ẹ̀dá kan ó wá ba ìlú jẹ́ mọ́ òun lórí.Ó ní òun ti pàṣẹ fún àwọn agbófinró kí wọ́n dá ṣẹ̀ríà fún Alétílápá ẹ̀dá.Ó wá kilọ̀ fún àwọn òbí kí wọ́n ó fi ewé ọmọ mọ̀ àwọn ọmọ wọn létí.
Ìlobùú àti Ẹ̀rìn-Ọ̀ṣun ti ń bá ara wọn ja ìjà ààlà ilẹ̀ ti pẹ́.Ní ọdún yìí nìkan, kò dín ní ẹgbẹ̀rún méjì ènìyàn tó ti di olóògbé tí ẹgbàágbèje sì ti di aláàbọ̀ ara àti aláìnílélórí látàri ogun àjàdijú tí àwọn ènìyàn náà ń jà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
