
Bàbá mi máa ń yin rédíò sókè lálá ni tó bá ti ń bá mí lò pọ̀
Ilé ẹjọ́ kan ni ìlú Àkúrẹ́ ti ní kí ọkùnrin Alágbàṣe àgbààyà akúmámojúidi kan,Moses Udoh tó ń gbé ní ojúlé ogún, àdúgbò Gbóníkì ní Láò ní ìlú Àkúrẹ́ lọ máa gba atégùn ni ibùdó Atóríṣe tó wà ní Olókùúta ní ìlú Àkúrẹ́ lórí ẹ̀ṣùn ifipabanilòpọ̀ àti ìdúnkookò mọ́ni titi di ọjọ́ kẹwàá oṣù Kejìlá yìí tí ìgbẹ́jọ́ yóò máa tẹ̀ síwájú lórí ẹ̀ṣùn náà.
Agbenuso fún ìjọba,Rìpẹ́tọ̀ Táíwò Oníyèrẹ́ sọ fún ile ẹjọ́ pé ní déédé agogo mẹ́wàá alẹ́ ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ni Moses Udoh kí ọmọbìnrin tó jẹ́ ọmọ bíbí inú rẹ mọ́lẹ̀ tó sì ń ṣe totomẹ́lẹ́tò pẹ̀lú ọmọdébìnrin náà eleyii tó tako abala kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìpín (a); àti abala kẹrìndínláàádọ́rùn-ún ìpín kejì òfin ipinlẹ̀ Oǹdó tí wọn ṣe àtúnṣe rẹ̀ lọ́dún 2021 .
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹjọ́ ọ̀hún,Adájọ Tèmilọlá Olújọbí ní ọ̀rọ̀ rírùn pátá gbáà ni Ọ̀rọ̀ náà,Ó wá ní kí wọn lọ fi ọ̀daràn náà si ibùdó Atóríṣe tó wà ní Olókùúta titi di ọjọ kẹwàá oṣù Kejìlá ọdún yìí tí ìgbẹ́jọ́ yóò máa tẹ̀ síwájú lórí ẹ̀ṣùn náà.
Nigba tí Ọmọbìnrin tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí ń sọ̀rọ̀, Ó ní òun kò ju ọmọ ọdún mẹwàá lọ ti bàbá òun ti ń fi ẹ̀kẹta itan rẹ̀ dárà sí òun lábẹ́.Ó ní tí ó bá ti mú òun wọlé tán ní yóò yí rédíò sókè lálá láti fi bo igbe òun mọ́lẹ̀.Ní kété tó bá ti ṣetán ni yóò dún ìkookò pé pípa ni òun yóò pa òun bi òun bá le sọ fún ẹ̀dá alààyè kankan.Ẹ̀rù ikú ló ń ba òun tí òun fi ṣe ọrọ náà ní Mẹ́numọ́ titi di ìgbà ti ẹ̀jẹ̀ ń jáde ní ìdí òun’tí òun fi sọ fún ẹ̀gbọ́n bàbá òun tó wá tú àṣírí náà síta.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
