Mọ̀tọ̀sẹ̀ Ló Kù,Ifá La fi Yan Aláàfin…Wándé Abímbólá

Ọ̀jọ̀gbọ́n Wándé Abímbólá

Àwíṣẹ ifá Àgbáyé tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ Gííwá ilé-, ẹ̀kọ́ gíga jùlọ Yunifásítì Ifẹ̀ tí ó ti di Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ báyìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wándé Abímbólá ti sàlàyé pé ifá ni àwọn lò láti yan Aláàfin tuntun,Ọmọ ọba Ọ̀wọ́adé sí ipò.

Olórí ọmọ ilé tí ó pọ̀ jùlọ nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ní Abuja tẹ́lẹ̀ rí yìí ní nígbà tí gbogbo rẹ̀ dí tán, tí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn Afọbajẹ látàrí àìdọ́gba nínú bí wọ́n ṣe pín owó ìbọ̀bẹ́ ti àwọn tó ń du oyè fún wọn ló ta Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́,Ṣèyí Mákindé nídìí kán láti bẹ òun lọ́wẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Oníṣẹ̀ṣe láti fi ifá tọ ẹni tí ó bá yẹ lóyè Aláàfin. Ò wá ròyìn Gómìnà Ṣèyí Mákindé gẹ́gẹ́ bíi olódodo ènìyàn tó sì mọ pàtàkì ise àti àsà Yorùbá.

Bí a kò bá ní gbàgbé,ó fẹ́rẹ̀ tó ọdún méjì báyìí tí Aláàfin àná,Ọbá Làmídì Ọláyíwọlá Adéyẹmí kẹta ti wàjà; láti ìgbà náà sì ni ìtẹ́ Aláàfin ti ṣófo.

Nínú ìtàn, Ọ̀yọ́ ni ibùdó Agbára fún ilẹ̀ Yorùbá.Nítorí náà, ipò Aláàfin kúrò ní kèrémí, kìí ṣe yọ̀bọ́kẹ́ .Ìyànsípò Aláàfin yìí ni yóò fòpin sí awuyewuye to ń gba ìgboro kan lórí ẹní tí ipò tuntun náà ti sí tàbí tí kò tọ́ sí

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×