Mi ò gbà kí Akpabio bá mí sùn ló ṣe ń bínú Mi… Natasha

Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò ààringbùngbùn Kogi nílé ìgbìmọ̀ Aṣòfin àgbà ní Abuja,Amòfin Natasha Akpoti Uduaghan tí fẹ̀sùn kan Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ Aṣofin Àgbà,Godswill Akpabio pé àìfi ara sílẹ̀ fún un láti bá òun ní àjọṣepọ̀ ló fa gbogbo ìdójúlé ti ó dojú lé òun tó fí ń yẹ àga ìjòkó nídìí òun.

Àná ni Natasha yajú-yamú ọ̀rọ̀ yìí lórí ẹ̀rọ Tẹlifísàn Aládàáni kan ní ìlú Abuja.Natasa ní Akpabio lerí léka pé ojú òun yóò rí àtàlátà baba Alàrùba bí òun bá kọ̀ látì tẹ́ ìdí sílẹ̀ fún òun,Lára ìgbésẹ̀ láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ ni bí ó ti yẹ àga ní ìdí òun ni gbàgede ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin.

Ẹ̀wẹ̀,Kenny Okulogo tíì ṣe akọ̀wé ìròyìn Sẹ́nétọ̀ Akpabio ti ṣẹ́ ẹsùn náà. Ó ní irọ́ to jìnnà sóòótọ́ ni ọ̀rọ̀ náà.

Bí a kò bá ní gbàgbé, ní nǹkan bíi ọdún márún-ún sẹ́yìn,nígbà tí Akpabio jẹ Mínísítà fún ìdàgbàsókè agbègbè Niger Delta, Arabinrin Joy Nunieh fí ẹ̀ṣùn kan án pé ó pe òun sí àgbègbè Apo ní ìlú Abuja pẹ̀lú ète láti bá òun lò pọ̀.Ó tẹ̀ síwájú pé ó fẹ́rẹ̀ tó ẹ̀ẹ̀mẹ́wàá tí òun ń gbá etí rẹ̀ ní àgbálé ti kò sile gbìn.

Lóòótọ́ , Akpabio ṣẹ́ ẹ̀ṣùn náà nígbà náà; Ṣùgbọ́n,Òní tete jìfìn,ọ̀la tete jìfìn, ṣé tete nikan ló ń bẹ lọ́fìn ni? Kín ló dé tí ọ̀rọ̀ gbogbo kìí ṣe l’órí Alábahun.Bí a bá ní ẹran oníwo ń bẹ ní ibikan, bí a bá dé ibẹ̀ tí a kò bá ìgalà tí a kò bá ẹtu,bó ṣe ìgbín, ó di dandan kí á bá.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×