Màá gba kámú lórí èsì ìdìbò Edo…Obaseki

Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo, Godwin Obaseki ti sọ yanya ni ìlú Benin tii ṣe olúìlú ìpínlẹ̀ náà pé ibí yòówù tí èsì ìbò sí ipò Gomina ipinle náà tí yóò wáyé ni ọjọ Sátidé ọjọ́ kọkànlélógún osù kẹsàn-án yìí bá já sí ní òun yóò gbà .

Obaseki fí ojú ọ̀rọ̀ yìí lédè lẹ́yìn ìpàdé Alátìlẹ̀kùnmọ́rí ṣe tó wáyé láàárín oun àti ọ̀gá àgbà yan-an-yán fún ètò àbò nílẹ̀ wa,Ọ̀gágun àgbà Cjristopher Gwabin Musa.

Gomina ipinle Edo ni ohun ti oun ń fẹ́ ni kí tẹ́rú-tọmọ ìpínlẹ̀ òun dìbò yan ẹni tó bá wù wọ́n nínú ìdìbò tí kò ní bayobáyo mínú.

Ó wá rọ ajọ INEC àtí àwọn elétò ààbò láti má ṣe ṣègbè leyin ẹgbẹ́ tàbí olóṣèlú kankan.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×