Òjò àrọ̀ìrọ̀dá kan tó rọ̀ lọ́jọ́ ẹtì ọjọ́ kẹrin oṣù kẹsàn-án ọdún yìí nílùú Oǹdó ní ìpínlẹ̀ Oǹdó ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn di aláìnílélórí, nígbà tí àwọn ènìyàn míìràn bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn, tí ọ̀kẹ́ àìmọye dúkìá sì ṣòfò látàrí làlúrí náà.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ sàlàyé pé àgbàrá òjò gba ọ̀nà kan tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn àrìnrìnàjò láti Ilé-ifẹ̀ kó leè wọ ìgboro Oǹdó nitori alagbalúgbú omi tó gba òpópónà náà ní ọ̀gangan ilé ìtura Esporta.
Bákan náà ni omi se ṣe ọṣẹ́ ní agbègbè Odòjọmu àtí Ìtańlá nibi ti omi tí gba mọ́tò àti ọ̀kadà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn, tó sì ṣé ọ̀nà mọ́ àwọn àrìnrìnàjò láti Ọ̀rẹ̀ àti Àkúrẹ́ pẹ̀lú àwọn mìíràn tó ń lọ láti agbègbè kan sí ìkejì láàrin ìlú ńlá náà.
Ọ̀kan lára àwọn ènìyàn tí ìṣẹ̀lẹ̀ òhun ṣojú rẹ̀,Onímọ̀ ẹ̀rọ Fẹ́mi Adétóyè sàlàyé pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló sùn sí ìrònà nígbà tí àwọn mìíràn fi òru wọlé.Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó ní “Agogo mọ́kànlá òru ni ìyàwó mi tó ń ṣe iṣẹ́ ní Yunifásítì Adéyemí tóo wọ ilé lánà-án .”
Ó wá rọ ìjọba láti tètè wá nǹkan ṣe sí àwọn ojú ọ̀nà tó ń gba dúkìá-gbẹ̀mí lọ́dọọdún náà.
Oníṣòwò kan ní agbègbè Odòjọmu, Arábìnrin Rahmata ní ìgbà kẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ rèé ní ọdún yìí nìkan tí irúfé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí yóò ṣẹlẹ̀ ní agbègbè náà.
Ọdọọdún ni àwọn irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí máa ń sẹlẹ̀ ní àwọn àdúgbò tí a dárúkọ yìí ní ìlú Oǹdó tó sì máa ń fi ọpọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá ṣòfò ní gbogbo ìgbà.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
