
Bí ìgbà tí àrá ń sán ni ìbọn ṣe ń dún lára ọkọ̀ èro GUO tó ń lọ sí Abuja ní ọjọ ìṣẹ́gun àná láàrin Àkùnù sí Àyèrẹ́ ni ìpínlè Kogi.
Óṣojúmipàtó tó fí ìṣẹ̀lẹ̀ náà léde lórí ẹ̀rọ Abẹ́yẹfò twitter rẹ̀.Gẹ́gẹ́ bó ti wí, ní kété tí mọ́tò náà kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n ń ṣàdédé gbọ́ ìró ìbon lọ́tùn-lósì tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì fara pa yánnayànna.ṣùgbọ́n wọn kò jí ẹnikẹni gbé.
Gbogbo ìgbà ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé máa ń wáyé ní ọ̀gangan ibi ti ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí sí.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
