Láìròtẹ́lẹ̀! Iná Ẹ̀rọ Amúnàwá Gbẹ̀mí Olè Ajíwáyàtú Ní Àkútè.

Ọwọ́ Pálábá olè Ajíwáyàtú kan tí ẹnì kankan kò mọ ẹyẹ tó ṣu ú ti ṣégi ní agbègbè Irewole ní Àkútè ni ipinlẹ̀ Ògùn nígbà tí ó ń gbìyànjú láti gé wáyà ẹ̀rọ amúnáwá àdúgbò náà tí iná sì dé lójijì.Lójú ẹsẹ̀ náà sì ni iná gba ẹ̀mí rẹ̀.

Ọgbẹ́ni Ràsídì Àjàgbé tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn tó ń gbé ní agbègbè náà ni ọjọ́ ti pẹ́ tí àwọn olè Alọkólóhunkígbe kò ti jẹ kí àwọn gbádùn iná mọ̀nàmọ́ná ní àdúgbò náà.Ṣé ọjọ́ gbogbo ni ti Olè, ọjọ́ kan ni ti Olóhun.

Alukoro àjọ Ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ ògùn,Ọmọlọlá Odùtọ́lá tó fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ ni ọ̀gá Ọlọ́pàá ipinlẹ náà ti gbé ìgbìmọ̀ olùṣèwádìí dìde lórí ọ̀rọ̀ náà.

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Scroll to Top
×