
Nítorí ojú ọjọ́ tó yí padà pẹ̀lú òjò tó ń rọ̀ yìí, kò sí àgbẹ̀ tí ara rẹ̀ le balẹ̀ láìlọ sí oko.Gbogbo wa la ṣáà mọ̀ pé ọ̀nà ọ̀fun, ọ̀nà ọ̀run ni,àti pé ebi kìí wọnú kí ọ̀rọ̀ mìíràn ó wọ̀ ọ́.
Nítorí ìpèníjà ètò àbò tó wáyé ní ìhà Àríwá Àkúrẹ́ lẹnu ọjọ́ mẹ́ta yìí,eléyìí tó ja okùn ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn agbègbè náà tó sì sọ wọ́n si inú hílàhílo àti ẹ̀rü bíbà láti lọ sí oko, ènìyàn yóò rò pé kò sí ọ̀kankan nínú wọn tí yóò tẹ oko mọ́ ní ọdún yìí, Ṣùgbọ́n,ọba ránni ní iṣẹ́,odò ọnà gbọ̀nà ni ọ̀rọ̀ ọ̀hún,iṣẹ́ ọba kò ṣe í kọ̀,odò ọbà kò sì ṣe í rọ́lù.Ohun gbogbo ló ṣe í mú mọ́ra,ebi kò jẹ́ ká mú ọjọ́ òhun jẹ; ìdí nìyii ti àwọn ènìyàn ọ̀hún fi kọjá lọ sí oko láìro ìkọlù àwọn Fúlàní darandaran lẹ́ẹ̀mejì.

Ikọ̀ ìròyìn Naija notes Yorùbá tó ṣe àbẹwò sí àgbègbè náà lónì-ín ọjọ́ ajé ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹta ọdún yìí fi àbọ̀ jẹ́ wa pé kẹ̀tíkẹ̀tí ni àwọn àgbẹ̀ agbègbè náà tù yááyáá sí oko kóówá wọn láti gbin onírúurú nǹkan ọ̀gbìn.Lára àwọn ìlú ti ikọ̀ ìròyìn wa dé ni Ìlú-Àbò,Adémẹ́kùn,Powerline,Ìsìnìgbò àti Òde-Ìgèdè .
Àgbẹ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ James Anya, tí ó bá wa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àdàmọ̀dì èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Benue ni òun,iṣẹ́ àgbẹ̀ ni òun yàn láàyò láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé òun wá,ìdágìrì àwọn Fúlàní ló lé òun kúrò ní ilé.Ìbànújẹ́ ńlá ló jẹ́ fún òun pé ogun tí òun ń sá fún ni ilé ni òun tún pàdé ni ẹ̀yìn odi.Ó wá rọ ìjọba kó bá àwọn mójú tó ètò àbò agbègbè náà kí oúnjẹ ó lé sùnwá bọ̀ ní ìpínlẹ̀ Òndó.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀,Àgbẹ̀ mìíràn, Arábìnrin Tọ́lání Idris ní lóòótọ́ ni ìjọba ń gbìyànjú ṣugbọn iyànjú wọn kò ì tó ní ìgbánnu ètò àbò.Ó ní ọkàn àwọn olùgbé agbègbè náà kò balẹ̀ rárá nítorí ìdágìrì láti ọwọ́ àwọn Fúlàní darandaran.

Oyè Oyèdọ̀tun jẹ́ gbajúgbajà Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Oníròyìn,Akéwì,Olórin,Ọ̀ǹkọ̀wé, àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn.Ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ìròyìn àti èdè Yorùbá ló fa ìdásílẹ̀ ìkànnì yìí.A ti fi ìkòkò ṣe ọbẹ̀,ó yá ẹ je ká tọ́ ọ wò..Oyinmọmọ!
